Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:3 - Yoruba Bible

3 Bí mo ti gbé ojú sókè, mo rí i tí àgbò kan dúró létí odò, ó ní ìwo meji tí ó ga sókè, ṣugbọn ọ̀kan gùn ju ekeji lọ. Èyí tí ó gùn jù ni ó hù kẹ́yìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Mo si gbé oju mi soke, mo si ri, si kiye si i, àgbo kan ti o ni iwo meji duro lẹba odò na: iwo mejeji na si ga, ṣugbọn ekini ga jù ekeji lọ, eyiti o ga jù li o jade kẹhin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Mo wo òkè mo sì rí àgbò kan tí ó ní ìwo méjì níwájú mi, ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ odò Ulai, àwọn ìwo náà sì gùn. Ṣùgbọ́n ọ̀kan gùn ju èkejì lọ, èyí tí ó gùn jù ni ó yọ jáde kẹ́yìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:3
25 Iomraidhean Croise  

Dafidi rí angẹli náà tí ó dúró ní agbede meji ayé ati ọ̀run, tí ó na idà ọwọ́ rẹ̀ sí orí Jerusalẹmu. Dafidi ati àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ bá dojúbolẹ̀.


“Èmi Kirusi, ọba Pasia kéde pé: OLUWA Ọlọrun ọ̀run ti fi gbogbo ìjọba ayé fún mi, ó sì ti pàṣẹ fún mi pé kí n kọ́ ilé kan fún òun ní Jerusalẹmu ní ilẹ̀ Juda.


Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn èké tí wọ́n ń san owó fún láti da ìpinnu àwọn ará Juda rú ní gbogbo àkókò ìjọba Kirusi, ọba Pasia, títí di àkókò Dariusi, ọba Pasia.


ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún àwọn ìjòyè, ati àwọn olórí, àwọn òṣìṣẹ́, ati àwọn olórí ogun Pasia ati ti Media, àwọn eniyan pataki pataki tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn gomina agbègbè rẹ̀.


Wò ó! N óo rú àwọn ará Media sókè sí wọn, àwọn tí wọn kò bìkítà fún fadaka bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ka wúrà sí. Wọn óo wá bá Babiloni jà.


Ìran tí a fi hàn mí yìí le: Àwọn oníjàgídíjàgan lọ digun kó ìkógun, abanǹkanjẹ́ sì ba nǹkan jẹ́. Ẹ̀yin ará Elamu, ẹ gòkè lọ! Ẹ̀yin ará Media, ẹ múra ogun! Mo ti fòpin sí òṣé ati ìjìyà tí Babiloni kó bá gbogbo eniyan.


èmi tí mo sọ fún Kirusi pé: ‘Ìwọ ni ọba tí n óo yàn tí yóo mú gbogbo ìpinnu mi ṣẹ;’ tí mo sọ fún Jerusalẹmu pé: ‘A óo tún odi rẹ̀ mọ,’ tí mo sì sọ fún Tẹmpili pé, ‘A óo tún fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀.’ ”


Ẹ pọ́n ọfà yín! Ẹ gbé asà yín! Nítorí OLUWA ti ru ẹ̀mí àwọn ọba Media sókè, nítorí pé ó ti pinnu láti pa Babiloni run. Ẹ̀san OLUWA ni, ẹ̀san nítorí tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó.


Bí mo ti gbójú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó wọ aṣọ funfun, ó fi àmùrè wúrà ṣe ìgbànú.


Lẹ́yìn rẹ ni ìjọba mìíràn yóo dìde tí kò ní lágbára tó tìrẹ. Lẹ́yìn èyí ni ìjọba kẹta, tí ó jẹ́ ti idẹ, yóo jọba lórí gbogbo ayé.


Dariusi, ará Mede, ẹni ọdún mejilelọgọta sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.


Nǹkan sì ń dára fún Daniẹli ní àkókò Dariusi ati Kirusi, àwọn ọba Pasia.


“Ẹranko keji dàbí àmọ̀tẹ́kùn, ó gbé ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan sókè. Ó gbé egungun ìhà mẹta há ẹnu, ó wa eyín mọ́ ọn. Mo sì gbọ́ tí ẹnìkan sọ fún un pé, ‘Dìde, kí o sì máa jẹ ẹran sí i.’


Ninu ìran náà, mo rí i pé mo wà ní Susa, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Elamu. Mo rí i pé mo wà létí odò Ulai.


“Àwọn ọba Pasia ati Media ni àgbò tí o rí, tí ó ní ìwo meji lórí.


Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí ìwo mààlúù mẹrin,


Bí mo tún ti gbé ojú sókè, mo rí ọkunrin kan tí ó mú okùn ìwọ̀n lọ́wọ́.


Mo tún gbé ojú sókè, mo bá rí ìwé kíká kan tí ń fò ní òfuurufú.


Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá jáde, ó ní, “Gbé ojú rẹ sókè kí o tún wo kinní kan tí ń bọ̀.”


Bí mo ti gbé ojú sókè ni mo rí àwọn obinrin meji tí wọn ń fi tagbára tagbára fò bọ̀, ìyẹ́ apá wọn dàbí ìyẹ́ ẹyẹ àkọ̀. Wọ́n hán agbọ̀n náà, wọ́n sì ń fò lọ.


Mo tún gbé ojú sókè, mo rí kẹ̀kẹ́ ogun mẹrin tí ń bọ̀ láàrin òkè meji; òkè idẹ ni àwọn òkè náà.


ó sì rí i bí àwọn ọmọ Israẹli ti pa àgọ́ wọn, olukuluku ẹ̀yà ni ààyè tirẹ̀. Ẹ̀mí Ọlọrun sì bà lé e,


Nígbà tí Joṣua súnmọ́ ìlú Jẹriko, ó gbé ojú sókè, ó sì rí i tí ọkunrin kan dúró níwájú rẹ̀ pẹlu idà lọ́wọ́. Joṣua lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó bi í pé, “Tiwa ni ò ń ṣe ni, tabi ti àwọn ọ̀tá wa?”


Mo tún rí ẹranko mìíràn tí ó jáde láti inú ilẹ̀. Ó ní ìwo meji bíi ti Ọ̀dọ́ Aguntan. Ó ń sọ̀rọ̀ bíi ti Ẹranko Ewèlè.


Mo bá rí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó dúró láàrin ìtẹ́ náà, àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin ati àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun náà yí i ká. Ọ̀dọ́ Aguntan náà dàbí ẹni pé wọ́n ti pa á. Ìwo meje ni ó ní ati ojú meje. Àwọn ojú meje yìí ni Ẹ̀mí Ọlọrun meje tí Ọlọrun rán sí gbogbo orílẹ̀ ayé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan