Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:16 - Yoruba Bible

16 Mo gbóhùn ẹnìkan láàrin bèbè kinni keji odò Ulai tí ó wí pé, “Geburẹli, sọ ìtumọ̀ ìran tí ọkunrin yìí rí fún un.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Emi si gbọ́ ohùn enia kan lãrin odò Ulai, ti o pè, ti o si wi pe, Gabrieli, mu ki eleyi moye iran na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Ulai, tí ó ń ké pé “Gebrieli, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:16
16 Iomraidhean Croise  

Kí o lè mọ ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí àwọn eniyan rẹ lẹ́yìn ọ̀la ni mo ṣe wá, nítorí ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni ìran tí o rí.”


Kò sí ẹni tí yóo gbèjà mi ninu nǹkan wọnyi àfi Mikaeli, olùṣọ́ Israẹli; Ṣugbọn n óo sọ ohun tí ó wà ninu Ìwé Òtítọ́ fún ọ.


Mo bá súnmọ́ ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀, mo bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí, ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ó ní,


Ninu ìran náà, mo rí i pé mo wà ní Susa, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Elamu. Mo rí i pé mo wà létí odò Ulai.


Mo bá bèèrè pé, “OLUWA mi, kí ni ìtumọ̀ kinní wọnyi?” Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì dáhùn pé, “N óo sọ ìtumọ̀ wọn fún ọ.”


“Sáré lọ sọ fún ọmọkunrin tí ó ní okùn ìwọ̀n lọ́wọ́ pé, eniyan ati ẹran ọ̀sìn yóo pọ̀ ní Jerusalẹmu tóbẹ́ẹ̀ tí a kò ní lè mọ odi yí i ká.


Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Geburẹli ni orúkọ mi, èmi ni mo máa ń dúró níwájú Ọlọrun. Ọlọrun ló rán mi láti bá ọ sọ̀rọ̀, ati láti sọ nǹkan ayọ̀ yìí fún ọ.


Ní oṣù kẹfa, Ọlọrun rán angẹli Geburẹli lọ sí ìlú kan ní Galili tí wọn ń pè ní Nasarẹti.


Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó ń bá a sọ̀rọ̀, ó ní, “Peteru dìde, pa ẹran kí o jẹ ẹ́!”


Àwọn ọkunrin tí ó ń bá a rìn dúró. Wọn kò sọ ohunkohun. Wọ́n ń gbọ́ ohùn eniyan, ṣugbọn wọn kò rí ẹnìkankan.


Ṣebí ẹ̀mí tí ó jẹ́ iranṣẹ ni gbogbo àwọn angẹli. A rán wọn láti ṣiṣẹ́ nítorí àwọn tí yóo jogún ìgbàlà.


Mo bá yipada láti wo ẹni tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Bí mo ti yipada, mo rí ọ̀pá fìtílà wúrà meje.


“Èmi Jesu ni mo rán angẹli mi láti jíṣẹ́ gbogbo nǹkan wọnyi fún ẹ̀yin ìjọ. Èmi gan-an ni gbòǹgbò ati ọmọ Dafidi. Èmi ni ìràwọ̀ òwúrọ̀.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan