Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:13 - Yoruba Bible

13 Ẹni mímọ́ kan sọ̀rọ̀; mo tún gbọ́ tí ẹni mímọ́ mìíràn dá ẹni tí ó kọ́ sọ̀rọ̀ lóhùn pé, “Ìran nípa ẹbọ sísun ojoojumọ yóo ti pẹ́ tó; ati ti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ń sọ nǹkan di ahoro; ati ìran nípa pípa ibi mímọ́ tì, ati ti àwọn ọmọ ogun tí wọ́n di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Mo si gbọ́ ẹni-mimọ́ ti nsọ̀rọ; ẹni-mimọ́ kan si wi fun ẹnikan ti nsọ̀rọ pe, Iran na niti ẹbọ ojojumọ, ati ti irekọja isọdahoro, ani lati fi ibi-mimọ́ ati ogun fun ni ni itẹmọlẹ yio ti pẹ to?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ ń sọ̀rọ̀, àti ẹni mímọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ fún un pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ìran yìí yóò fi wá sí ìmúṣẹ—ìran nípa ẹbọ ojoojúmọ́, ìṣọ̀tẹ̀ tí ó mú ìsọdahoro wa, àní láti fi ibi mímọ́ àti ogun ọ̀run fún ni ní ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:13
38 Iomraidhean Croise  

Yóo ti pẹ́ tó, Ọlọrun, tí ọ̀tá yóo máa fi ọ́ ṣẹ̀fẹ̀? Ṣé títí ayé ni ọ̀tá yóo máa gan orúkọ rẹ ni?


A kò rí àsíá wa mọ́, kò sí wolii mọ́; kò sì sí ẹnìkan ninu wa tí ó mọ bí ìṣòro wa yóo ti pẹ́ tó.


Yóo ti pẹ́ tó, OLUWA? Ṣé títí ayé ni o óo máa bínú ni? Àbí owú rẹ yóo máa jó bí iná?


Majẹmu tí ẹ bá ikú dá yóo wá di òfo, àdéhùn yín pẹlu ibojì yóo sì di asán. Nígbà tí jamba bá ń ṣẹlẹ̀ káàkiri, yóo máa dé ba yín.


Mo bá bi í pé: “OLUWA mi, títí di ìgbà wo?” Ó sì dáhùn pé: “Títí tí àwọn ìlú yóo fi di ahoro, láìsí ẹni tí yóo máa gbé inú wọn; títí tí ilé yóo fi tú láì ku ẹnìkan, títí tí ilẹ̀ náà yóo fi di ahoro patapata.


Fún ìgbà díẹ̀, ilé mímọ́ rẹ jẹ́ ti àwa eniyan mímọ́ rẹ; ṣugbọn àwọn ọ̀tá wa ti wó o lulẹ̀.


Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fún wa ní ọmọkunrin kan. Òun ni yóo jọba lórí wa. A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ-Aládé alaafia.


Ọpọlọpọ àwọn darandaran ni wọ́n ti ba ọgbà àjàrà mi jẹ́, wọ́n ti tẹ oko mi mọ́lẹ̀, wọ́n sọ oko mi dáradára di aṣálẹ̀.


Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo wá, wọn yóo sọ Tẹmpili ati ibi ààbò di aláìmọ́, wọn yóo dáwọ́ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo dúró, wọn yóo sì gbé ohun ìríra tíí fa ìsọdahoro kalẹ̀.


“Láti ìgbà tí wọn yóo mú ẹbọ ojoojumọ kúrò, tí wọn yóo gbé ohun ìríra sí ibi mímọ́, yóo jẹ́ eedegbeje ọjọ́ ó dín ọjọ́ mẹ́wàá (1,290).


Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?”


“Nígbà tí mo sùn, mo rí igi kan láàrin ayé, lójú ìran, igi náà ga lọpọlọpọ.


“Ní ojúran, lórí ibùsùn mi, mo rí olùṣọ́ kan, Ẹni Mímọ́,


Olùṣọ́, Ẹni Mímọ́ tí ọba rí tí ó sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run, tí ó ń wí pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀ kí o sì pa á run, ṣugbọn kí ó ku kùkùté ati gbòǹgbò rẹ̀ ninu ilẹ̀, kí ó wà ninu ìdè irin ati ti idẹ, ninu pápá oko tútù, kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ káàkiri fún ọdún meje.’


Mo bá súnmọ́ ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀, mo bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí, ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ó ní,


“Ó ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi báyìí pé: ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóo wà láyé, tí yóo sì yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìyókù. Yóo ṣẹgun gbogbo ayé, yóo tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, yóo sì fọ́ ọ túútúú.


Ìjòyè yìí yóo bá ọpọlọpọ dá majẹmu ọdún meje tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Fún ìdajì ọdún meje náà, yóo fi òpin sí ẹbọ rírú ati ọrẹ. Olùsọdahoro yóo gbé ohun ìríra ka téńté orí pẹpẹ ní Jerusalẹmu. Ohun ìríra náà yóo sì wà níbẹ̀ títí tí ìgbẹ̀yìn tí Ọlọrun ti fàṣẹ sí yóo fi dé bá olùsọdahoro náà.”


mo sì bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó bá dá mi lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn alágbára ayé tí wọ́n fọ́n Juda, Israẹli, ati Jerusalẹmu ká.”


Ẹ óo sá àsálà gba ọ̀nà pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó pín òkè náà sí meji. Ẹ óo sá bí àwọn baba ńlá yín ti sá nígbà tí ilẹ̀ mì tìtì ní àkókò Usaya, ọba Juda, OLUWA, Ọlọrun yín yóo wá dé, pẹlu gbogbo àwọn eniyan mímọ́ rẹ̀.


“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ Ọmọ àfi Baba; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó mọ Baba, àfi Ọmọ, àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.


“Nígbà náà ni ẹ óo rí ohun ẹ̀gbin tí wolii Daniẹli ti sọ tẹ́lẹ̀, tí ó dúró ní ibi mímọ́ (ìwọ olùkàwé yìí, jẹ́ kí ohun tí ò ń kà yé ọ).


“Ṣugbọn nígbà tí ẹ bá rí ẹ̀gbin burúkú náà tí ó dúró níbi tí kò yẹ– (kí ó yé ẹni tí ń ka ìwé yìí)– nígbà náà, kí àwọn tí ó wà ní ilẹ̀ Judia sálọ sí orí òkè.


“Baba mi ti fi ohun gbogbo lé mi lọ́wọ́. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́, àfi Baba. Kò sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ; àtúnfi àwọn tí Ọmọ bá fẹ́ fi Baba hàn fún.”


“Nígbà tí ẹ bá rí i tí ogun yí ìlú Jerusalẹmu ká, kí ẹ mọ̀ pé àkókò tí yóo di ahoro súnmọ́ tòsí.


Idà ni a óo fi pa wọ́n. A óo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè. Àwọn tí kì í ṣe Juu yóo wó ìlú Jerusalẹmu palẹ̀, títí àkókò tí a fi fún wọn yóo fi pé.


Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn.


OLUWA wá láti orí òkè Sinai, ó yọ gẹ́gẹ́ bí oòrùn láti Edomu, ó ràn sórí àwọn eniyan rẹ̀ láti òkè Parani. Ó wá láti ọ̀dọ̀ ẹgbaarun àwọn ẹni mímọ́, ó gbé iná tí ń jò lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀.


Kí Oluwa fi agbára fun yín, kí ọkàn yín lè wà ní ipò mímọ́, láìní àléébù, níwájú Ọlọrun Baba wa nígbà tí Oluwa wa Jesu bá farahàn pẹlu gbogbo àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.


Irú ìyà ńlá wo ni ẹ rò pé Ọlọrun yóo fi jẹ ẹni tí ó kẹ́gàn Ọmọ rẹ̀, tí ó rò pé nǹkan lásán ni ẹ̀jẹ̀ majẹmu tí a fi yà á sọ́tọ̀, tí ó sì ṣe àfojúdi sí Ẹ̀mí tí a fi gba oore-ọ̀fẹ́?


Ọlọrun fihan àwọn wolii wọnyi pé ohun tí wọn ń sọ kì í ṣe fún àkókò tiwọn bíkòṣe fún àkókò tiyín. Nisinsinyii a ti waasu nǹkan wọnyi fun yín nípa ìyìn rere tí ó ti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, tí a rán láti ọ̀run wá fun yín. Àwọn angẹli garùn títí láti rí nǹkan wọnyi.


Nípa àwọn wọnyi ni Enọku tí ó jẹ́ ìran keje sí Adamu sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé, “Mo rí Oluwa tí ó dé pẹlu ẹgbẹẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun àwọn angẹli rẹ̀ mímọ́,


Má wulẹ̀ wọn àgbàlá Tẹmpili tí ó wà lóde, nítorí a ti fi fún àwọn alaigbagbọ. Wọn yóo gba ìlú mímọ́ fún oṣù mejilelogoji.


Àwọn náà kígbe pé, “Oluwa mímọ́ ati olóòótọ́, nígbà wo ni ìwọ yóo ṣe ìdájọ́ fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí ìwọ yóo gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ wa lára wọn?”


Angẹli OLUWA náà dáhùn pé, “Kí ló dé tí o fi ń bèèrè orúkọ mi nígbà tí ó jẹ́ pé ìyanu ni?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan