Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:12 - Yoruba Bible

12 A fi ogun náà ati ẹbọ sísun ojoojumọ lé e lọ́wọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀, a sì já òtítọ́ lulẹ̀. Gbogbo ohun tí ìwo náà ń ṣe, ni ó ṣe ní àṣeyọrí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 A si fi ogun le e lọwọ pẹlu ẹbọ ojojumọ nitori irekọja, o si ja otitọ lulẹ, o si nṣe eyi, o si nri rere.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 A fún un ní ẹgbẹ́ ogun ọ̀run àti ẹbọ ojoojúmọ́ nítorí ìwà ọlọ̀tẹ̀ ẹ rẹ̀: ó sọ òtítọ́ nù nínú gbogbo ohun tó ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:12
14 Iomraidhean Croise  

Àwọn olè ń gbé ilé wọn ní alaafia, àwọn tí wọn ń mú Ọlọrun bínú wà ní àìléwu, àwọn tí ó jẹ́ pé agbára wọn ni Ọlọrun wọn.


Òdodo rẹ wà títí lae, òtítọ́ sì ni òfin rẹ.


Má gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ rẹ lẹ́nu mi rárá, nítorí ìrètí mi ń bẹ ninu ìlànà rẹ.


Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ OLUWA sí, wọn kò sì bìkítà fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, OLUWA yóo sọ wọ́n di ilẹ̀, kò sì ní gbé wọn dìde mọ́.


A fi ọwọ́ rọ́ ẹjọ́ ẹ̀tọ́ sẹ́yìn, òdodo sì takété. Òtítọ́ ti ṣubú ní gbangba ìdájọ́, ìdúróṣinṣin kò rọ́nà wọlé.


Olódodo ni ọ́, OLUWA, nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́; sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ. Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú?


Ọba Siria yóo wá pada sí ilẹ̀ rẹ̀ pẹlu gbogbo ìkógun rẹ̀. Ṣugbọn yóo pinnu ní ọkàn rẹ̀ láti gbógun ti majẹmu mímọ́ Ọlọrun ati Israẹli. Nígbà tí ó bá ṣe bí ó ti fẹ́ tán, yóo pada sí ilẹ̀ rẹ̀.


“Bí mo ti ń wò ó, mo rí i ti ìwo yìí ń bá àwọn eniyan mímọ́ jà, tí ó sì ń ṣẹgun wọn,


Mo rí i tí àgbò náà bẹ̀rẹ̀ sí kàn sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, ati sí ìhà àríwá ati sí ìhà gúsù, kò sí ẹranko tí ó lè dúró níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bí ó ti wù ú, ó sì ń gbéraga.


A fún un ní agbára láti gbógun ti àwọn eniyan Ọlọrun ati láti ṣẹgun wọn. A tún fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè ati oríṣìíríṣìí èdè ati gbogbo eniyan.


Nígbà tí Dafidi gbọ́ pé Saulu ń gbèrò ibi, ó pe Abiatari alufaa kí ó mú aṣọ efodu wá, láti ṣe ìwádìí lọ́wọ́ Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan