Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 8:1 - Yoruba Bible

1 Ní ọdún kẹta tí Beṣasari jọba ni èmi Daniẹli rí ìran kan lẹ́yìn ti àkọ́kọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 LI ọdun kẹta ijọba Belṣassari ọba, iran kan fi ara hàn fun mi, ani emi Danieli, lẹhin iran ti emi ri ni iṣaju.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà tí ó di ọdún kẹta ìjọba Belṣassari ọba, èmi Daniẹli rí ìran kan èyí tí mo ti rí tẹ́lẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 8:1
11 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹrin, ní ọgbọ̀n ọdún, èmi, Isikiẹli, ọmọ Busi, wà láàrin àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ Babiloni. A wà lẹ́bàá odò Kebari, mo bá rí i tí ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀; mo sì rí ìran Ọlọrun.


Ọlọrun fún àwọn ọdọmọkunrin mẹrẹẹrin yìí ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati òye; Daniẹli sì ní ìmọ̀ láti túmọ̀ ìran ati àlá.


Ní àkókò náà, èmi Daniẹli ń ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹta.


Èmi nìkan ni mo rí ìran yìí, àwọn tí wọ́n wà pẹlu mi kò rí i, ṣugbọn ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì sápamọ́.


Lẹ́yìn tí ó bá jọba, ìjọba rẹ̀ yóo pín sí ọ̀nà mẹrin. Àwọn ọba tí yóo jẹ lẹ́yìn rẹ̀ kò ní jẹ́ láti inú ìran rẹ̀, kò sì ní sí èyí tí yóo ní agbára tó o ninu wọn; nítorí a óo gba ìjọba rẹ̀, a óo sì fún àwọn ẹlòmíràn.


Ní ọdún kinni tí Beṣasari jọba ní Babiloni, Daniẹli lá àlá, o sì rí àwọn ìran kan nígbà tí ó sùn lórí ibùsùn rẹ̀. Ó bá kọ kókó ohun tí ó rí lójú àlá náà sílẹ̀.


“Ìran tí mo rí yìí bà mí lẹ́rù pupọ, ọkàn mi sì dààmú.


“Òpin ọ̀rọ̀ nípa ìran náà nìyí. Ẹ̀rù èrò ọkàn mi bà mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí ojú mi yipada, ṣugbọn inú ara mi ni mo mọ ọ̀rọ̀ náà sí.”


Nígbà tí èmi Daniẹli rí ìran náà, bí mo ti bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀, ni ẹnìkan bá yọ níwájú mi tí ó dàbí eniyan.


Ninu ìran náà, mo rí i pé mo wà ní Susa, olú-ìlú tí ó wà ní agbègbè Elamu. Mo rí i pé mo wà létí odò Ulai.


èmi, Daniẹli bẹ̀rẹ̀ sí ka ọ̀rọ̀ OLUWA, mò ń ronú lórí ohun tí Jeremaya, wolii sọ, pé Jerusalẹmu yóo dahoro fún aadọrin ọdún.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan