Daniẹli 7:9 - Yoruba Bible9 “Bí mo ti ń wo ọ̀kánkán, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí a tẹ́. Ẹni Ayérayé sì jókòó lórí ìtẹ́ tirẹ̀, aṣọ rẹ̀ funfun bíi ẹ̀gbọ̀n òwú. Irun orí rẹ̀ náà dàbí irun aguntan funfun, ìtẹ́ rẹ̀ ń jó bí ahọ́n iná, kẹ̀kẹ́ abẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sì dàbí iná. Faic an caibideilBibeli Mimọ9 Mo si wò titi a fi sọ̀ itẹ́ wọnni kalẹ titi Ẹni-àgba ọjọ na fi joko, aṣọ ẹniti o fún gẹgẹ bi ẹ̀gbọn owu, irun ori rẹ̀ si dabi irun agutan ti o mọ́: itẹ rẹ̀ jẹ ọwọ iná, ayika-kẹkẹ rẹ̀ si jẹ jijo iná. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní9 “Bí mo ṣe ń wò, “a gbé ìtẹ́ ọba kan kalẹ̀, ẹni ìgbàanì jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, Aṣọ rẹ̀ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú; irun orí rẹ̀ funfun bí òwú, ìtẹ́ ọba rẹ̀ rí bí ọwọ́ iná. Àwọn kẹ̀kẹ́ rẹ ń jó bí i iná. Faic an caibideil |
Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún.