Daniẹli 7:7 - Yoruba Bible7 “Lẹ́yìn èyí, ninu ìran tí mo rí ní òru náà, ẹranko kẹrin tí mo rí jáni láyà, ó bani lẹ́rù, ó sì lágbára pupọ. Ó tóbi, irin sì ni eyín rẹ̀. A máa fọ́ nǹkan túútúú, á jẹ ẹ́ ní àjẹrun, á sì fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀, ìwo mẹ́wàá ni ó ní. Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Lẹhin eyi, mo ri ni iran oru, si kiyesi i, ẹranko kẹrin ti o burujù, ti o si lẹrù, ti o si lagbara gidigidi; o si ni ehin irin nla: o njẹ o si nfọ tũtu, o si fi ẹsẹ rẹ̀ tẹ̀ iyokù mọlẹ: o si yatọ si gbogbo awọn ẹranko ti o ṣiwaju rẹ̀; o si ni iwo mẹwa. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 “Lẹ́yìn èyí, nínú ìran mi ní òru mo tún rí ẹranko kẹrin, ó dẹ́rùbà ni, ó dáyà fo ni, ó sì lágbára gidigidi. Ó ní eyín irin ńlá; ó ń jẹ, ó sì ń fọ́ túútúú, ó sì fi ẹsẹ̀ tẹ èyí tókù mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko ti ìṣáájú, ó sì ní ìwo mẹ́wàá. Faic an caibideil |
Ẹranko tí o rí yìí ti wà láàyè nígbà kan rí, ṣugbọn kò sí láàyè mọ́ nisinsinyii. Ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò, tí yóo gòkè wá láti inú ọ̀gbun jíjìn, tí yóo wá lọ sí ibi ègbé. Nígbà tí wọ́n bá rí ẹranko náà ẹnu yóo ya àwọn tí ó ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, nítorí ó ti wà láàyè, ṣugbọn kò sí láàyè nisinsinyii, ṣugbọn yóo tún pada yè.