Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 7:4 - Yoruba Bible

4 Ekinni dàbí kinniun, ó sì ní ìyẹ́ bíi ti idì. Mò ń wò ó títí tí ìyẹ́ rẹ̀ fi fà tu. A gbé e dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ mejeeji bí eniyan. Ó sì ń ronú bí eniyan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ẹranko kini dabi kiniun, o si ni iyẹ-apa idì: mo si wò titi a fi fà iyẹ-apa rẹ̀ wọnni tu, a si gbé e soke kuro ni ilẹ, a mu ki o fi ẹsẹ duro bi enia, a si fi aiya enia fun u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 “Ẹranko kìn-ín-ní dàbí i kìnnìún, ó sì ní ìyẹ́ apá a idì: mo sì wò títí a fi fa ìyẹ́ apá rẹ̀ náà tu, a sì gbé e sókè kúrò ní ilẹ̀, a mú kí ó fi ẹsẹ̀ dúró bí ènìyàn, a sì fi àyà ènìyàn fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 7:4
27 Iomraidhean Croise  

“Saulu ati Jonatani, àyànfẹ́ ati eniyan rere, wọn kì í ya ara wọn nígbà ayé wọn, nígbà tí ikú sì dé, wọn kò ya ara wọn. Wọ́n yára ju àṣá lọ, wọ́n sì lágbára ju kinniun lọ.


kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti eniyan tí ó dàbí ìdin, tabi ọmọ eniyan tí ó dàbí ekòló lásánlàsàn!”


OLUWA, da ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ bò wọ́n, jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ pé aláìlágbára eniyan ni àwọn.


Bíi kinniun tí ó fi ihò rẹ̀ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni OLUWA fi àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀, ilẹ̀ wọn sì ti di ahoro nítorí idà apanirun ati ibinu gbígbóná OLUWA.


Ẹ wò ó! Ó ń bọ̀ bí ìkùukùu, kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ dàbí ìjì. Àwọn ẹṣin rẹ̀ yára ju àṣá lọ. A gbé, nítorí ìparun dé bá wa.


Kinniun kan ti jáde lọ láti inú igbó tí ó wà; ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n máa ń run àwọn orílẹ̀-èdè ti gbéra; ó ti jáde kúrò ní ipò rẹ̀, láti sọ ilẹ̀ yín di ahoro. Yóo pa àwọn ìlú yín run, kò sì ní sí eniyan ninu wọn mọ́.


OLUWA ní, “Wò ó, ẹnìkan yóo fò wá bí ẹyẹ idì, yóo sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ lé Moabu lórí.


Wò ó, bí kinniun tií yọ ní aginjù odò Jọdani láti kọlu agbo aguntan, bẹ́ẹ̀ ni n óo yọ sí Edomu n óo sì mú kí ó sá kúrò lórí ilẹ̀ rẹ̀ lójijì. N óo sì yan ẹnikẹ́ni tí ó bá wù mí láti máa ṣe àkóso ibẹ̀; nítorí ta ló dàbí mi? Ta ló lè yẹ̀ mí lọ́wọ́ wò? Olùṣọ́-aguntan wo ló lè dúró dè mí?


Àwọn tí wọn ń lépa wa yára ju idì tí ń fò lójú ọ̀run lọ. Wọ́n ń lé wa lórí òkè, wọ́n sì ba dè wá ninu aṣálẹ̀.


Wí fún wọn pé, OLUWA Ọlọrun ní idì ńlá kan wá sí Lẹbanoni, apá rẹ̀ tóbi, ìrù rẹ̀ sì gùn, ó sì ní ìyẹ́ aláràbarà. Ó bá bà lé ṣóńṣó orí igi kedari kan,


“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún ọba Tire pé OLUWA ní, ‘Nítorí pé ìgbéraga kún ọkàn rẹ, o sì ti sọ ara rẹ di oriṣa, o sọ pé o jókòó ní ibùjókòó àwọn oriṣa láàrin òkun; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan ni ọ́, o kì í ṣe oriṣa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń rò pé o gbọ́n bí àwọn oriṣa,


Ṣé o óo lè sọ pé oriṣa kan ni ọ́ lójú àwọn tí wọ́n bá fẹ́ pa ọ́? Nígbà tí wọ́n bá ń ṣá ọ lọ́gbẹ́, ṣé eniyan ni o óo wá pe ara rẹ àbí oriṣa.


Ọlọrun fi gbogbo eniyan jìn ọ́, níbi yòówù tí wọn ń gbé, ati gbogbo ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, pé kí o máa jọba lórí wọn, ìwọ ni orí wúrà náà.


“Ní àkókò gan-an tí iyè mi pada bọ̀ sípò, ògo, ọlá, ati iyì ìjọba mi náà sì tún pada sọ́dọ̀ mi. Àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ìjòyè mi wá mi kàn, wọ́n gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀, ìjọba mi tún fi ìdí múlẹ̀, mo sì níyì ju ti àtẹ̀yìnwá lọ ní gbogbo ọ̀nà.


Ní ti àwọn ẹranko tí ó kù, a gba àṣẹ wọn, ṣugbọn a dá wọn sí fún àkókò kan, àní fún ìgbà díẹ̀.


“Ẹranko keji dàbí àmọ̀tẹ́kùn, ó gbé ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan sókè. Ó gbé egungun ìhà mẹta há ẹnu, ó wa eyín mọ́ ọn. Mo sì gbọ́ tí ẹnìkan sọ fún un pé, ‘Dìde, kí o sì máa jẹ ẹran sí i.’


“Níbi tí òkú ẹran bá wà, níbẹ̀ ni àwọn gúnnugún yóo péjọ sí.


OLUWA yóo gbé orílẹ̀-èdè kan, tí ẹ kò gbọ́ èdè wọn, dìde si yín láti òpin ayé; wọn óo yára bí àṣá.


Ẹranko náà tí mo rí dàbí àmọ̀tẹ́kùn. Ẹsẹ̀ rẹ̀ dàbí ti ìkookò. Ẹnu rẹ̀ dàbí ti kinniun. Ẹranko Ewèlè náà fún un ní agbára rẹ̀, ati ìtẹ́ rẹ̀ ati àṣẹ ńlá rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan