Daniẹli 7:3 - Yoruba Bible3 Àwọn ẹranko ńláńlá mẹrin bá jáde láti inú òkun. Ọ̀kan kò jọ̀kan ni àwọn mẹrẹẹrin. Faic an caibideilBibeli Mimọ3 Ẹranko mẹrin nla si ti inu okun jade soke, nwọn si yatọ si ara wọn. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní3 Ẹranko ńlá mẹ́rin tí ó yàtọ̀ sí ara wọn, jáde láti inú Òkun náà. Faic an caibideil |
Ẹranko tí o rí yìí ti wà láàyè nígbà kan rí, ṣugbọn kò sí láàyè mọ́ nisinsinyii. Ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò, tí yóo gòkè wá láti inú ọ̀gbun jíjìn, tí yóo wá lọ sí ibi ègbé. Nígbà tí wọ́n bá rí ẹranko náà ẹnu yóo ya àwọn tí ó ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, nítorí ó ti wà láàyè, ṣugbọn kò sí láàyè nisinsinyii, ṣugbọn yóo tún pada yè.