Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 7:23 - Yoruba Bible

23 “Ó ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi báyìí pé: ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóo wà láyé, tí yóo sì yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìyókù. Yóo ṣẹgun gbogbo ayé, yóo tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, yóo sì fọ́ ọ túútúú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

23 Bẹ̃li o wipe, Ẹranko kẹrin nì yio ṣe ijọba kẹrin li aiye, eyiti yio yàtọ si gbogbo ijọba miran, yio pa gbogbo aiye rẹ́, yio si tẹ̀ ẹ molẹ, yio si fọ ọ tũtu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 “Ó ṣe àlàyé yìí fún mi pé: ‘Ẹranko kẹrin ni ìjọba kẹrin tí yóò wà ní ayé. Yóò yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ìjọba yòókù yóò sì pa gbogbo ayé run, yóò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, yóò sì fọ́ ọ́ sí wẹ́wẹ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 7:23
5 Iomraidhean Croise  

Nígbà tí ó bá yá, ìjọba kẹrin yóo dé, tí yóo le koko bíi irin (nítorí pé irin a máa fọ́ nǹkan sí wẹ́wẹ́ ni); bíi irin ni ìjọba yìí yóo fọ́ àwọn tí wọ́n wà ṣáájú rẹ̀ túútúú.


títí tí Ẹni Ayérayé fi dé, tí ó dá àwọn ẹni mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ láre; tí ó sì tó àkókò fún àwọn ẹni mímọ́ láti gba ìjọba.


Àwọn ìwo mẹ́wàá dúró fún àwọn ọba mẹ́wàá, tí yóo jáde lára ìjọba kẹrin yìí. Ọ̀kan yóo jáde lẹ́yìn wọn, tí yóo yàtọ̀ sí wọn, yóo sì borí mẹta ninu àwọn ọba náà.


“Lẹ́yìn èyí, ninu ìran tí mo rí ní òru náà, ẹranko kẹrin tí mo rí jáni láyà, ó bani lẹ́rù, ó sì lágbára pupọ. Ó tóbi, irin sì ni eyín rẹ̀. A máa fọ́ nǹkan túútúú, á jẹ ẹ́ ní àjẹrun, á sì fi ẹsẹ̀ tẹ àjẹkù rẹ̀ mọ́lẹ̀. Ó yàtọ̀ sí gbogbo àwọn ẹranko tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀, ìwo mẹ́wàá ni ó ní.


Ní àkókò náà, àṣẹ kan jáde láti ọ̀dọ̀ Kesari Augustu pé kí gbogbo ayé lọ kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìjọba.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan