Daniẹli 7:22 - Yoruba Bible22 títí tí Ẹni Ayérayé fi dé, tí ó dá àwọn ẹni mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ láre; tí ó sì tó àkókò fún àwọn ẹni mímọ́ láti gba ìjọba. Faic an caibideilBibeli Mimọ22 Titi Ẹni-àgba ọjọ nì fi de, ti a si fi idalare fun awọn enia-mimọ ti Ọga-ogo; titi akokò si fi de ti awọn enia-mimọ́ jogun ijọba na. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní22 títí ẹni ìgbàanì fi dé, ó sì ṣe ìdájọ́ ìdáláre fún àwọn ẹni mímọ́ Ọ̀gá-ògo, àsìkò náà sì dé nígbà tí àwọn ẹni mímọ́ náà jogún ìjọba. Faic an caibideil |
Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún.