Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 7:16 - Yoruba Bible

16 Mo bá súnmọ́ ọ̀kan ninu àwọn tí wọ́n dúró níbẹ̀, mo bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí, ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ó ní,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Mo sunmọ ọkan ninu awọn ti o duro lapakan, mo si bi i lere otitọ gbogbo nkan wọnyi. Bẹ̃li o sọ fun mi, o si fi itumọ nkan wọnyi hàn fun mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Mo lọ bá ọ̀kan nínú àwọn tí ó dúró níbẹ̀, mo sì bi í léèrè òtítọ́ ìtumọ̀ nǹkan wọ̀nyí. “Ó sọ fún mi, ó sì túmọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún mi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 7:16
14 Iomraidhean Croise  

Iná ń ṣàn jáde bí odò níwájú rẹ̀. Ẹgbẹẹgbẹrun ọ̀nà ẹgbẹẹgbẹrun ni àwọn tí ń ṣe iranṣẹ fún un, ọ̀kẹ́ àìmọye sì ni àwọn tí wọ́n dúró níwájú rẹ̀. Ìdájọ́ bẹ̀rẹ̀, a sì ṣí àwọn ìwé sílẹ̀.


‘Àwọn ọba ńlá mẹrin tí yóo jẹ láyé ni àwọn ẹranko ńláńlá mẹrin tí o rí.


Ó wá sí ẹ̀bá ibi tí mo dúró sí. Bí mo ti rí i, ẹ̀rù bà mí, mo dojúbolẹ̀. Ó bá sọ fún mi pé, “Ìwọ ọmọ eniyan, mo fẹ́ kí o mọ̀ pé ìran ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la ni ohun tí o rí.”


Ó wá ṣe àlàyé fún mi, ó ní, “Daniẹli, àlàyé ìran tí o rí ni mo wá ṣe fún ọ.


mo sì bèèrè ìtumọ̀ ohun tí mo rí lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀. Ó bá dá mi lóhùn pé, “Àwọn ìwo wọnyi dúró fún àwọn alágbára ayé tí wọ́n fọ́n Juda, Israẹli, ati Jerusalẹmu ká.”


Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ bá bọ́ siwaju, angẹli mìíràn sì lọ pàdé rẹ̀, Angẹli àkọ́kọ́ sọ fún ekeji pé,


“Bí o bá tẹ̀lé ọ̀nà mi, tí o sì pa òfin mi mọ́, o óo di alákòóso ilé mi ati àwọn àgbàlá rẹ̀. N óo sì fún ọ ní ipò láàrin àwọn tí wọ́n dúró wọnyi.


Ọ̀kan ninu àwọn àgbààgbà mẹrinlelogun yìí wá sọ fún mi pé, “Má sunkún mọ́! Wò ó! Kinniun ẹ̀yà Juda, ọmọ Dafidi, ti borí. Ó le ṣí ìwé náà ó sì le tú èdìdì meje tí a fi dì í.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan