Daniẹli 7:11 - Yoruba Bible11 “Mo wò yíká nítorí ọ̀rọ̀ ńláńlá tí ìwo kékeré yìí ń fi ẹnu sọ, mo sì rí i tí wọ́n pa ẹranko náà, tí wọ́n sì jó òkú rẹ̀ níná. Faic an caibideilBibeli Mimọ11 Nigbana ni mo wò nitori ohùn ọ̀rọ nla ti iwo na nsọ: mo si wò titi a fi pa ẹranko na, a si pa ara rẹ̀ run, a si sọ ọ sinu ọwọ iná ti njo. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní11 “Nígbà náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí ní wò, nítorí àwọn ọ̀rọ̀ ìgbéraga tí ìwo náà ń sọ, mo wò títí a fi pa ẹranko náà, a sì pa á run, a sì jù ú sínú iná tí ń jó. Faic an caibideil |
Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn ìtẹ́ kan tí eniyan jókòó lórí wọn. A fún àwọn eniyan wọnyi láṣẹ láti ṣe ìdájọ́. Àwọn ni ọkàn àwọn tí wọ́n ti bẹ́ lórí nítorí ẹ̀rí tí wọ́n jẹ́ nípa Jesu ati nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Àwọn ni wọ́n kò júbà ẹranko náà tabi ère rẹ̀, wọn kò sì gba àmì rẹ̀ siwaju wọn tabi sí ọwọ́ wọn. Wọ́n tún wà láàyè, wọ́n sì jọba pẹlu Kristi fún ẹgbẹrun ọdún.