Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:7 - Yoruba Bible

7 gbogbo àwọn alabojuto, àwọn olórí, àwọn ìgbìmọ̀, ati àwọn gomina kó ara wọn jọ, wọ́n sì fi ohùn ṣọ̀kan pé kí ọba ṣe òfin kan pé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ òun ọba. Ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kabiyesi, kí wọ́n jù ú sinu ihò kinniun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Gbogbo awọn olori alakoso ijọba, awọn bãlẹ ati awọn arẹ bãlẹ, awọn ìgbimọ, ati olori ogun jọ gbìmọ pọ̀ lati fi ofin ọba kan lelẹ, ati lati paṣẹ lile kan, pe ẹnikẹni ti o ba bère nkan lọwọ Ọlọrun tabi eniakenia niwọn ọgbọ̀n ọjọ bikoṣepe lọwọ rẹ, ọba, a o gbé e sọ sinu ihò kiniun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Àwọn alákòóso ọba, ìjòyè, baálẹ̀, olùdámọ̀ràn, àti àwọn olórí gbìmọ̀ pọ̀ wí pé kí ọba kéde òfin kan pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, yàtọ̀ fún ìwọ ọba, a ó ju ẹni náà sí inú ihò kìnnìún.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:7
25 Iomraidhean Croise  

Ó fara pamọ́ bíi kinniun tí ó wà ní ibùba; ó fara pamọ́ láti ki aláìní mọ́lẹ̀; ó mú aláìní, ó sì fi àwọ̀n fà á lọ.


Àwọn ọba ayé kó ara wọn jọ, àwọn ìjòyè gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n dojú kọ OLUWA ati àyànfẹ́ rẹ̀.


Wò ó bí wọ́n ṣe lúgọ dè mí! OLUWA, àwọn jàǹdùkú eniyan kó ara wọn jọ láti pa mí lára, láìṣẹ̀, láìrò.


Ìwọ, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli, jí gìrì, kí o jẹ gbogbo orílẹ̀-èdè níyà; má da ẹnìkan kan sí ninu àwọn tí ń fi ìwà ọ̀dàlẹ̀ pète ibi.


Wọ́n fẹ́ ré e bọ́ láti ipò ọlá rẹ̀. Inú wọn a máa dùn sí irọ́. Wọ́n ń fi ẹnu wọn súre, ṣugbọn ní ọkàn wọn, èpè ni wọ́n ń ṣẹ́.


Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jùmọ̀ pète pèrò; wọ́n dá majẹmu láti dojú kọ ọ́.


Ǹjẹ́ o lè ní àjọṣe pẹlu àwọn ìkà aláṣẹ, àwọn tí ń fi òfin gbé ìwà ìkà ró?


Àwọn ará Kalidea bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ọba pẹ́! Rọ́ àlá rẹ fún àwa iranṣẹ rẹ, a óo sì túmọ̀ rẹ̀.”


ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná tí ń jó.


Ó pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn olórí ati àwọn gomina, àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn akápò, àwọn onídàájọ́ ati àwọn alákòóso ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè Babiloni wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí òun gbé kalẹ̀.


Gbogbo àwọn baálẹ̀ ìgbèríko, àwọn olórí, àwọn gomina, ati àwọn ìgbìmọ̀ ọba, kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí i pé iná kò jó àwọn ọkunrin wọnyi, irun orí wọn kò rùn, ẹ̀wù wọn kò yipada, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tilẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn.


Ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó sin ère náà, lẹsẹkẹsẹ ni a óo gbé e sọ sinu adágún iná.”


Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Daniẹli, kí wọ́n sì jù ú sinu ihò kinniun. Ṣugbọn ó sọ fún Daniẹli pé, “Ọlọrun rẹ tí ò ń sìn láìsinmi yóo gbà ọ́.”


Ọlọrun mi ti rán angẹli rẹ̀, ó ti dí àwọn kinniun lẹ́nu, wọn kò sì pa mí lára. Nítorí pé n kò jẹ̀bi níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ṣe nǹkan burúkú sí ìwọ ọba.”


Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ ranti ète tí Balaki, ọba Moabu pa si yín, ati ìdáhùn tí Balaamu, ọmọ Beori, fún un. Ẹ ranti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ninu ìrìn àjò yín láti Ṣitimu dé Giligali, kí ẹ lè mọ iṣẹ́ ìgbàlà tí OLUWA ṣe.”


Akọ kinniun a máa fa ẹran ya fún àwọn ọmọ rẹ̀, a sì máa lọ́ ẹran lọ́rùn pa fún àwọn abo rẹ̀; a máa kó ẹran tí ó bá pa ati èyí tí ó fàya sinu ihò rẹ̀.


Àwọn Farisi bá jáde lọ láti gbèrò nípa rẹ̀, bí wọn óo ṣe lè pa á.


Wọ́n ń gbèrò ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe lè fi ẹ̀tàn mú Jesu kí wọ́n lè pa á.


Gbàrà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn olórí alufaa pẹlu àwọn àgbà ati àwọn amòfin ati gbogbo Ìgbìmọ̀ yòókù forí-korí, wọ́n de Jesu, wọ́n bá fà á lọ láti fi lé Pilatu lọ́wọ́ fún ìdájọ́.


Àwọn olórí alufaa bá pinnu láti pa Lasaru,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan