Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:4 - Yoruba Bible

4 Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina wọnyi ń wá ẹ̀sùn sí Daniẹli lẹ́sẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìjọba, ṣugbọn wọn kò rí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n lè kà sí i lẹ́sẹ̀. Wọn kò ká ohunkohun mọ́ ọn lọ́wọ́ nítorí olóòótọ́ eniyan ni. Wọn kò bá àṣìṣe kankan lọ́wọ́ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Nigbana ni awọn alakoso, ati awọn arẹ bãlẹ nwá ẹ̀sùn si Danieli lẹsẹ̀ nipa ọ̀rọ ijọba, ṣugbọn nwọn kò le ri ẹ̀sùn tabi ẹ̀ṣẹkẹṣẹ lọwọ rẹ̀; niwọn bi on ti jẹ olododo enia tobẹ̃ ti a kò si ri iṣina tabi ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Nítorí èyí, gbogbo àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ ń gbèrò láti wá ẹ̀ṣẹ̀ kà sí Daniẹli lọ́rùn nínú ètò ìṣèjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan kà sí i lọ́rùn, wọn kò rí ìwà ìbàjẹ́ kankan tí ó ṣe, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ kò sì ní ìwà ìjáfara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:4
32 Iomraidhean Croise  

Ó bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ a lè rí irú ọkunrin yìí, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀?”


Ẹ̀rù bẹ̀rẹ̀ sí bà wọ́n nígbà tí Josẹfu mú wọn wọ ilé rẹ̀, wọ́n ń wí fún ara wọn pé, “Nítorí owó tí wọ́n fi sí ẹnu àpò wa níjelòó ni wọ́n fi kó wa wọlé, kí ó lè rí ẹ̀sùn kà sí wa lẹ́sẹ̀, kí ó lè fi wá ṣe ẹrú, kí ó sì kó àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.”


Olódodo a máa kórìíra alaiṣootọ, eniyan burúkú a sì kórìíra eniyan rere.


Mo rí i pé gbogbo làálàá tí eniyan ń ṣe ati gbogbo akitiyan rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀, ó ń ṣe é nítorí pé eniyan ń jowú aládùúgbò rẹ̀ ni. Asán ati ìmúlẹ̀mófo ni èyí pàápàá.


Wọ́n bá dáhùn pé, “Ẹ wá, kí á gbìmọ̀ ibi sí Jeremaya, nítorí pé òfin kò ní parun lọ́dọ̀ àwọn alufaa, ìmọ̀ràn kò ní tán lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n, ọ̀rọ̀ Ọlọrun kò sì ní ṣàì máa wà lẹ́nu àwọn wolii. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á fi ọ̀rọ̀ ẹnu wa pa á, ẹ má sì jẹ́ kí á fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kankan.”


OLUWA, gbogbo àbá tí wọn ń dá ni o mọ̀, o mọ gbogbo ète tí wọn ń pa láti pa mí. Má dárí ìwà ibi wọn jì wọ́n, má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ níwájú rẹ. Jẹ́ kí wọn ṣubú níwájú rẹ, nígbà tí inú bá ń bí ọ ni kí o bá wọn wí.”


Nítorí mò ń gbọ́ tí ọpọlọpọ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, “Ìpayà wà lọ́tùn-ún lósì, ẹ lọ fẹjọ́ rẹ̀ sùn. Ẹ jẹ́ kí á fẹjọ́ rẹ̀ sùn.” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń wí, tí wọn sì ń retí ìṣubú mi. Wọ́n ń sọ pé, “Bóyá yóo bọ́ sọ́wọ́ ẹlẹ́tàn, ọwọ́ wa yóo sì tẹ̀ ẹ́; a óo sì gbẹ̀san lára rẹ̀.”


Ẹ máa wá alaafia ìlú tí mo ko yín lọ, ẹ máa gbadura sí OLUWA fún un, nítorí pé ninu alaafia rẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ti ní alaafia.


Àwọn ará Kalidea kan wá siwaju ọba, wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn Juu pẹlu ìríra, wọ́n ní,


nítorí pé Daniẹli, tí ọba sọ ní Beteṣasari, ní ìmọ̀ ati òye láti túmọ̀ àlá, ati láti ṣe àlàyé ohun ìjìnlẹ̀, ati láti yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú. Ranṣẹ pe Daniẹli yìí, yóo sì sọ ìtumọ̀ fún ọ.”


Ọlọrun mi ti rán angẹli rẹ̀, ó ti dí àwọn kinniun lẹ́nu, wọn kò sì pa mí lára. Nítorí pé n kò jẹ̀bi níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ṣe nǹkan burúkú sí ìwọ ọba.”


Wọ́n ń gbèrò ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe lè fi ẹ̀tàn mú Jesu kí wọ́n lè pa á.


Pilatu ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọ́n fi mú un wá sọ́dọ̀ òun.


Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣọ́ ọ. Wọ́n rán àwọn amí kí wọ́n ṣe bí eniyan rere, kí wọ́n lè ká ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu, kí wọn wá fi lé gomina lọ́wọ́, kí gomina dá sẹ̀ría fún un.


Wọn kò lè mú ọ̀rọ̀ mọ́ ọn lẹ́nu lójú gbogbo eniyan. Ìdáhùn rẹ̀ yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n bá dákẹ́.


Àwọn olórí alufaa ati àwọn amòfin ń wá ọ̀nà bí wọn yóo ti ṣe pa Jesu nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn eniyan.


Pilatu tún jáde lọ sóde, ó sọ fún àwọn Juu pé, “Mò ń mú un tọ̀ yín bọ̀ wá sóde, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi kò rí i pé ó jẹ̀bi ohunkohun.”


Bí mo ti ń ṣe ni n óo tún máa ṣe, kí n má baà fi ààyè sílẹ̀ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ ṣe ìgbéraga pé iṣẹ́ wọn dàbí tiwa.


kí ẹ lè jẹ́ Ọmọ Ọlọrun, tí kò lẹ́bi tí kò sì ní àléébù, ọmọ Ọlọrun tí ó pé, láàrin àwọn ìran tí ọ̀nà wọn wọ́, tí ìwà wọn sì ti bàjẹ́. Láàrin irú àwọn eniyan wọnyi ni ẹ̀ ń tàn bí ìmọ́lẹ̀ ninu ayé,


Nítorí náà mo fẹ́ kí àwọn opó tí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ tún lọ́kọ, kí wọ́n bímọ, kí wọ́n ní ilé tiwọn. Bí wọ́n bá ṣe bẹ́ẹ̀ wọn kò ní fi ààyè sílẹ̀ fún ọ̀tá láti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́.


Kí gbolohun ẹnu rẹ jẹ́ ti ọmọlúwàbí, tí ẹnìkan kò ní lè fi bá ọ wí. Èyí yóo mú ìtìjú bá ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe alátakò nígbà tí kò bá rí ohun burúkú kan sọ nípa wa.


Kí ìgbé-ayé yín láàrin àwọn abọ̀rìṣà jẹ́ èyí tí ó dára, tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ yín ní àìdára, sibẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà rere yín, wọn yóo yin Ọlọrun lógo ní ọjọ́ ìdájọ́.


Ṣugbọn kí ẹ dáhùn pẹlu ìrẹ̀lẹ̀ ati ìwà pẹ̀lẹ́. Ẹ ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́, tí ó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bá ń sọ ọ̀rọ̀ yín ní àìdára, ojú yóo ti àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ àbùkù nípa yín, nígbà tí wọn bá rí ìgbé-ayé yín gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ.


Ṣugbọn baba ati ìyá rẹ̀ kò mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà ní ọwọ́ OLUWA ninu, nítorí pé OLUWA ti ń wá ọ̀nà láti mú àwọn ará Filistia nítorí pé, àwọn ni wọ́n ń mú àwọn ọmọ Israẹli sìn ní àkókò yìí.


Àwọn eniyan náà dáhùn pé, “Rárá o, o kò rẹ́ wa jẹ rí, o kò ni wá lára, bẹ́ẹ̀ ni o kò sì gba ohunkohun lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni rí.”


Ó ń ṣe àṣeyọrí nítorí pé OLUWA wà pẹlu rẹ̀.


Ahimeleki dáhùn pé, “Ta ló jẹ́ olóòótọ́ bíi Dafidi láàrin gbogbo àwọn olórí ogun rẹ? Ṣebí àna rẹ ni, ó sì jẹ́ olórí àwọn ọmọ ogun tí wọn ń ṣọ́ ọ ati eniyan pataki ninu ilé rẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan