Daniẹli 6:3 - Yoruba Bible3 Ṣugbọn Daniẹli tún ta gbogbo àwọn alámòójútó ati gomina náà yọ nítorí ẹ̀mí tí kò lẹ́gbẹ́ tí ó wà ninu rẹ̀. Ọba sì ń gbèrò láti fi gbogbo ọ̀rọ̀ ìjọba lé e lọ́wọ́. Faic an caibideilBibeli Mimọ3 Danieli yi si bori gbogbo awọn alakoso ati arẹ bãlẹ wọnyi, nitoripe ẹmi titayọ wà lara rẹ̀: ọba si ngbiro lati fi i ṣe olori gbogbo ijọba. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní3 Daniẹli ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láàrín àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ nítorí ẹ̀mí tí ó tayọ wà lára rẹ̀ dé bi pé ọba sì ń gbèrò láti fi ṣe olórí i gbogbo ìjọba. Faic an caibideil |
Ó kígbe sókè pé kí wọ́n tètè lọ pe àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea ati àwọn awòràwọ̀ wá. Nígbà tí wọ́n dé, ọba sọ fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka ohun tí wọ́n kọ sára ògiri yìí, tí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fi aṣọ elése àlùkò dá a lọ́lá, n óo ní kí wọ́n fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, yóo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ninu ìjọba mi.”