Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:12 - Yoruba Bible

12 Wọ́n wá siwaju ọba, wọ́n sọ nípa àṣẹ tí ó pa pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ rẹ̀, ati pé ẹnikẹ́ni tí ó bá rú òfin yìí, a óo jù ú sinu ihò kinniun. Ọba dáhùn, ó ní: “Dájúdájú, òfin Mede ati Pasia ni, tí a kò lè yipada.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

12 Nigbana ni nwọn wá, nwọn si wi niwaju ọba niti aṣẹ ọba pe, Kò ṣepe iwọ fi ọwọ sinu iwe pe, ẹnikan ti o ba bère ohunkohun lọwọ Ọlọrun tabi lọwọ enia kan niwọn ọgbọ̀n ọjọ, bikoṣe lọwọ rẹ, ọba, pe a o gbé e sọ sinu iho kiniun? Ọba si dahùn o wipe, Otitọ li ọ̀ran na, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, ti a kò gbọdọ pada.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Wọ́n lọ sí iwájú ọba, wọ́n sì rán ọba létí nípa òfin tí ó ṣe pé, “Ìwọ kò ha fi ọwọ́ sí òfin wí pé ní ìwọ̀n ọgbọ̀n ọjọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn, láì bá ṣe ìwọ ọba, a ó gbé e jù sínú ihò kìnnìún?” Ọba sì dáhùn pé, “Àṣẹ náà dúró síbẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn ará Media àti Persia, èyí tí a kò le è parẹ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:12
7 Iomraidhean Croise  

Nítorí náà bí ó bá wu ọba, kí ọba pàṣẹ, kí á sì kọ ọ́ sinu ìwé òfin Pasia ati ti Media, tí ẹnikẹ́ni kò lè yipada, pé Faṣiti kò gbọdọ̀ dé iwájú ọba mọ́, kí ọba sì fi ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn tí ó sàn jù ú lọ.


Àwọn ọkunrin wọnyi gbìmọ̀, wọ́n sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, o mọ̀ pé òfin Mede ati ti Pasia ni pé òfin tí ọba bá ṣe kò gbọdọ̀ yipada.”


Nisinsinyii, kabiyesi, ẹ fi ọwọ́ sí òfin yìí, kí ó lè fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin Mede ati Pasia tí kò gbọdọ̀ yipada.”


Nígbà tí àwọn olówó ọdọmọbinrin náà rí i pé ọ̀nà oúnjẹ wọ́n ti dí, wọ́n ki Paulu ati Sila mọ́lẹ̀, wọ́n fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ní ọjà.


Nígbà tí ó ti gba irú àṣẹ báyìí, ó sọ wọ́n sinu àtìmọ́lé ti inú patapata, ó tún fi ààbà kan ẹsẹ̀ wọn mọ́ igi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan