Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:10 - Yoruba Bible

10 Nígbà tí Daniẹli gbọ́ pé wọ́n ti fi ọwọ́ sí òfin náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó wọ yàrá òkè lọ, ó ṣí fèrèsé ilé rẹ̀ sílẹ̀, sí apá Jerusalẹmu. Ó kúnlẹ̀, ó ń gbadura, ó sì ń yin Ọlọrun, nígbà mẹta lojoojumọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Nigbati Danieli si ti mọ̀ pe a kọ iwe na tan, o wọ ile rẹ̀ lọ; (a si ṣi oju ferese yara rẹ̀ silẹ siha Jerusalemu) o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ nigba mẹta lõjọ, o gbadura, o si dupẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi on ti iṣe nigba atijọ ri.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Lóòótọ́, Daniẹli mọ̀ pé a ti fi ọwọ́ sí ìwé òfin náà, síbẹ̀ ó wọ ilé e rẹ̀ lọ, nínú yàrá òkè, ó ṣí fèrèsé èyí tí ó kọjú sí Jerusalẹmu sílẹ̀. Ó kúnlẹ̀ lórí orúnkún un rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, ó gbàdúrà, ó fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:10
47 Iomraidhean Croise  

Máa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ iranṣẹ rẹ ati adura àwọn ọmọ Israẹli, eniyan rẹ, nígbà tí wọ́n bá kọjú sí ilé yìí, tí wọ́n sì gbadura, máa gbọ́ tiwa láti ibùgbé rẹ lọ́run, kí o sì máa dáríjì wá.


gbọ́ adura tí wọ́n bá gbà, ati ẹ̀bẹ̀ tí ẹnikẹ́ni tabi gbogbo Israẹli, àwọn eniyan rẹ, bá bẹ̀, nítorí ìpọ́njú ọkàn olukuluku wọn. Tí wọ́n bá gbé ọwọ́ wọn sókè, tí wọ́n sì kọjú sí ilé ìsìn yìí,


“Nígbà tí àwọn eniyan rẹ bá lọ dojú kọ àwọn ọ̀tá wọn lójú ogun, níbikíbi tí o bá rán wọn lọ, tí wọ́n bá kọjú sí ìlú tí o yàn yìí, ati ilé ìsìn tí mo kọ́ fún ọ, tí wọ́n sì gbadura,


Nígbà ti Solomoni parí adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sí OLUWA, ó dìde kúrò níwájú pẹpẹ níbi tí ó kúnlẹ̀ sí, tí ó sì gbé ọwọ́ sókè.


Solomoni ti ṣe pẹpẹ bàbà kan, ó gbé e sí àgbàlá ilé náà. Gígùn ati ìbú rẹ̀ jẹ́ igbọnwọ marun-un (mita 2¼), gíga rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹta (1.3 mita). Solomoni gun orí pẹpẹ yìí, níbi tí gbogbo eniyan ti lè rí i. Ó kúnlẹ̀, ó gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Ọlọrun;


tí wọ́n bá ronupiwada tọkàntọkàn ninu ìgbèkùn níbi tí a kó wọn lẹ́rú lọ, tí wọ́n gbadura sí ìhà ilẹ̀ tí o fún àwọn baba wọn, ati sí ìlú tí o ti yàn, ati sí ilé tí mo kọ́ fún ìjọ́sìn ní orúkọ rẹ,


Ní àkókò ẹbọ àṣáálẹ́, mo dìde kúrò níbi tí mo ti ń gbààwẹ̀ pẹlu aṣọ ati agbádá mi tí ó ya, mo kúnlẹ̀, mo sì tẹ́wọ́ sí OLUWA Ọlọrun mi, mo gbadura pé:


Ṣugbọn mo dá a lóhùn pé, “Ṣé irú mi ni ó yẹ kí ó sá lọ? Àbí irú mi ni ó yẹ kí ó sá lọ sinu tẹmpili kí ó lọ máa gbé ibẹ̀? N kò ní lọ.”


N óo máa yin OLUWA ní gbogbo ìgbà; ìyìn rẹ̀ yóo máa wà ní ẹnu mi nígbà gbogbo.


Ṣugbọn nípa ọ̀pọ̀ ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀, èmi óo wọ inú ilé rẹ; n óo fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ wólẹ̀, n óo sì kọjúsí tẹmpili mímọ́ rẹ.


Mò ń ráhùn tọ̀sán-tòru, mo sì ń kérora; OLUWA óo gbọ́ ohùn mi.


Ṣàánú mi, OLUWA, nítorí ìwọ ni mò ń kígbe pè tọ̀sán-tòru.


Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á jọ́sìn, kí á tẹríba, ẹ jẹ́ kí á kúnlẹ̀ níwájú OLUWA, Ẹlẹ́dàá wa!


Wọ́n bá sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ìgbèkùn Juda kò kà ọ́ sí, kò sì pa òfin rẹ mọ́. Ṣugbọn ìgbà mẹta lóòjọ́ níí máa gbadura.”


Mo gbadura sí OLUWA Ọlọrun mi, mo jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi. Mo ní, “OLUWA Ọlọrun, tí ó tóbi, tí ó bani lẹ́rù, tíí máa ń pa majẹmu ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ pẹlu gbogbo àwọn tí ó bá fẹ́ ẹ, tí wọ́n sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́.


Nígbà náà ni mo sọ pé, ‘A ti ta mí nù kúrò níwájú rẹ; báwo ni n óo ṣe tún rí tẹmpili mímọ́ rẹ?’


Ó wí fún ọkunrin náà tí ọwọ́ rẹ̀ rọ pé, “Dìde dúró ní ààrin àwùjọ.”


“Bí ẹnìkan bá fẹ́ wá sọ́dọ̀ mi, bí kò bá kórìíra baba rẹ̀ ati ìyá rẹ̀, ati iyawo rẹ̀, ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati ẹ̀gbọ́n, ati àbúrò rẹ̀, lọkunrin ati lobinrin, tí ó fi mọ́ ẹ̀mí òun pàápàá, kò lè jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.


Ó bá kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó lọ siwaju díẹ̀ sí i. Ó kúnlẹ̀, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí gbadura.


Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń bá ìrìn àjò wọn lọ, tí wọ́n súnmọ́ Jọpa, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbadura ní nǹkan agogo mejila ọ̀sán.


Àwọn yìí kò mutí yó bí ẹ ti rò, nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni.


Ṣugbọn n kò ka ẹ̀mí mi sí ohunkohun tí ó ní iye lórí fún ara mi. Ohun tí mò ń lépa ni láti parí iré ìje mi ati iṣẹ́ tí mo gbà lọ́wọ́ Oluwa mi Jesu, èyí ni pé kí n tẹnu mọ́ ìyìn rere oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.


Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kúnlẹ̀ pẹlu gbogbo wọn, ó sì gbadura.


Nígbà tí ọjọ́ tí a óo gbé níbẹ̀ pé, a gbéra láti máa bá ìrìn àjò wa lọ. Gbogbo wọn ati àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn sìn wá dé ẹ̀yìn odi. A bá kúnlẹ̀ lórí iyanrìn ní èbúté, a gbadura.


Ní agogo mẹta ọ̀sán, Peteru ati Johanu gòkè lọ sí Tẹmpili ní àkókò adura.


Ǹjẹ́ nisinsinyii, Oluwa, ṣe akiyesi bí wọ́n ti ń halẹ̀, kí o sì fún àwọn iranṣẹ rẹ ní ìgboyà ní gbogbo ọ̀nà láti lè sọ ọ̀rọ̀ rẹ.


“Ẹ lọ dúró ninu Tẹmpili kí ẹ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn eniyan.”


Peteru pẹlu àwọn aposteli dáhùn pé, “A níláti gbọ́ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ.


Ni ó bá kúnlẹ̀, ó kígbe, ó ní, “Oluwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” Nígbà tí ó sọ báyìí tán, ó kú.


Peteru bá ti gbogbo wọn jáde, ó kúnlẹ̀, ó gbadura. Ó bá kọjú sí òkú náà, ó ní, “Tabita, dìde.” Ni Tabita bá lajú, ó rí Peteru, ó bá dìde jókòó.


Nítorí èyí ni mo ṣe ń fi ìkúnlẹ̀ gbadura sí Baba,


Èyí fún ọpọlọpọ ninu àwọn onigbagbọ tí wọ́n mọ ìdí tí mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n ní ìgboyà gidigidi láti máa waasu ìyìn rere láì bẹ̀rù.


gẹ́gẹ́ bí igbẹkẹle ati ìrètí mi pé n kò ní rí ohun ìtìjú kan. Ṣugbọn bí mo ti máa ń gbé Kristi ga ninu ara mi pẹlu ìgboyà nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ gan-an náà ni n óo tún máa gbé e ga nisinsinyii ìbáà jẹ́ pé mo wà láàyè tabi pé mo kú.


Ẹ má ṣe jẹ́ kí ohunkohun dààmú yín, ṣugbọn ninu gbogbo adura ati ẹ̀bẹ̀ yín, ẹ máa fi àwọn ìbéèrè yín siwaju Ọlọrun pẹlu ọpẹ́.


Ohun gbogbo tí ẹ bá ń ṣe, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ni tabi pé ẹ̀ ń ṣe nǹkankan ni, ẹ máa ṣe é ní orúkọ Oluwa Jesu. Ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun Baba nípasẹ̀ rẹ̀.


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa rú ẹbọ ìsìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo nípasẹ̀ Jesu. Èyí ni ohun tí ó yẹ gbogbo ẹni tí ó bá ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á fi ìgboyà súnmọ́ ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́, kí á lè rí àánú gbà, ati nípa oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, kí á lè rí ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.


Má bẹ̀rù ohunkohun tí ò ń bọ̀ wá jìyà. Èṣù yóo gbé ẹlòmíràn ninu yín jù sinu ẹ̀wọ̀n láti fi dán yín wò. Fún ọjọ́ mẹ́wàá ẹ óo ní ìṣòro pupọ. Ṣugbọn jẹ́ olóòótọ́ dé ojú ikú, Èmi yóo sì fún ọ ní adé ìyè.


Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ibẹ̀ ni Satani tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Sibẹ o di orúkọ mi mú, o kò bọ́hùn ninu igbagbọ ní ọjọ́ tí wọ́n pa Antipasi ẹlẹ́rìí òtítọ́ mi ní ìlú yín níbi tí Satani fi ṣe ilé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan