Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 6:1 - Yoruba Bible

1 Dariusi ṣètò láti yan ọgọfa (120) gomina láti ṣe àkóso ìjọba rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 O ṣe didùn inu Dariusi lati fi ọgọfa arẹ bãlẹ sori ijọba na, ti yio wà lori gbogbo ijọba;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ó dára lójú Dariusi láti yan ọgọ́fà àwọn baálẹ̀ sórí ìjọba,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 6:1
9 Iomraidhean Croise  

Ní àkókò tí Ahasu-erusi jọba ní ilẹ̀ Pasia, ìjọba rẹ̀ tàn dé agbègbè mẹtadinlaadoje (127), láti India títí dé Kuṣi ní ilẹ̀ Etiopia.


Kí àwọn orílẹ̀-èdè múra láti gbógun tì í, kí àwọn ọba ilẹ̀ Media múra, pẹlu àwọn gomina wọn, ati àwọn ẹmẹ̀wà wọn, ati gbogbo ilẹ̀ tí ó wà lábẹ́ wọn.


“Ní ọdún kinni ìjọba Dariusi ará Mede, mo dúró tì í láti mú un lọ́kàn le ati láti bá a fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀.


Ó pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn olórí ati àwọn gomina, àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn akápò, àwọn onídàájọ́ ati àwọn alákòóso ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè Babiloni wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí òun gbé kalẹ̀.


Dariusi, ará Mede, ẹni ọdún mejilelọgọta sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.


Ó yan àwọn mẹta láti máa ṣe àbojútó gbogbo wọn, Daniẹli sì jẹ́ ọ̀kan ninu wọn. Àwọn mẹta wọnyi ni àwọn ọgọfa (120) gomina náà yóo máa jábọ̀ fún.


Ní ọdún kinni tí Dariusi, ọmọ Ahasu-erusi, ará Mede, jọba ní Babiloni,


tabi aṣojú ọba gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó rán láti jẹ àwọn tí ó bá ń ṣe burúkú níyà, ati láti yin àwọn tí ó bá ń ṣe rere.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan