Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:9 - Yoruba Bible

9 Ọkàn Beṣasari dàrú, ojú rẹ̀ yipada. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dààmú, wọn kò sì mọ ohun tí wọ́n lè ṣe.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nigbana ni ẹ̀ru nla ba Belṣassari ọba gidigidi, oju rẹ̀ si yipada lori rẹ̀, ẹ̀ru si ba awọn ijoye rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Nígbà náà ni Belṣassari ọba bínú gidigidi, ojú u rẹ̀ sì túbọ̀ dàrú sí i. Ẹ̀rù sì ba àwọn ìjòyè Belṣassari.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:9
12 Iomraidhean Croise  

Ó ta ọfà rẹ̀ jáde, ó sì fọ́n wọn ká, ó jẹ́ kí mànàmáná kọ, ó sì tú wọn ká.


ìwárìrì mú wọn níbẹ̀; ìrora sì bá wọn bí obinrin tí ń rọbí.


Ẹ bèèrè, kí ẹ sì ṣe ìwádìí; ǹjẹ́ ọkunrin lè lóyún kí ó sì bímọ? Kí ló wá dé tí mo rí gbogbo ọkunrin, tí wọn ń dáwọ́ tẹ ìbàdí bí obinrin tí ń rọbí? Kí ló dé tí gbogbo yín fajúro?


A gbúròó wọn, ọwọ́ wa rọ; ìdààmú dé bá wa, bí ìrora obinrin tí ó ń rọbí.


Èmi nìkan ni mo kù tí mo sì rí ìran ńlá yìí. Kò sí agbára kankan fún mi mọ́; ojú mi sì yipada, ó wá rẹ̀ mí dẹẹ.


Ní ọdún keji tí Nebukadinesari gun orí oyè, ó lá àwọn àlá kan; àlá náà bà á lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi lè sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà.


Ojú ọba yipada, ẹ̀rù bà á, ara rẹ̀ ń gbọ̀n, orúnkún rẹ̀ sì ń lu ara wọn.


Nígbà tí Hẹrọdu gbọ́, ara rẹ̀ kò balẹ̀, ara gbogbo eniyan ìlú Jerusalẹmu náà kò sì balẹ̀.


Àwọn ọba ayé, àwọn ọlọ́lá, àwọn ọ̀gágun, àwọn olówó, àwọn alágbára, ati gbogbo eniyan: ẹrú ati òmìnira, gbogbo wọn lọ sápamọ́ sinu ihò òkúta ati abẹ́ àpáta lára àwọn òkè.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan