Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:6 - Yoruba Bible

6 Ojú ọba yipada, ẹ̀rù bà á, ara rẹ̀ ń gbọ̀n, orúnkún rẹ̀ sì ń lu ara wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Nigbana ni oju ọba yipada, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀, tobẹ̃ ti amure ẹ̀gbẹ rẹ̀ tu, ẽkunsẹ̀ rẹ̀ mejeji si nlù ara wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Ojú ọba sì yí padà, ẹ̀rù sì bà á, tó bẹ́ẹ̀ tí orúnkún ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rẹ̀ fi ń gbá ara wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:6
21 Iomraidhean Croise  

Agbára mi ti lọ, ó ti ṣàn dànù bí omi, gbogbo egungun mi ti yẹ̀ lóríkèéríkèé; ọkàn mi dàbí ìda, ó ti yọ́.


Jẹ́ kí ojú wọn ṣú, kí wọn má lè ríran; kí gbogbo ara wọn sì máa gbọ̀n rìrì.


Ẹ gbé ọwọ́ tí kò lágbára ró. Ẹ fún orúnkún tí kò lágbára ní okun.


Kò rẹ ẹnikẹ́ni ninu wọn, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò fẹsẹ̀ kọ. Ẹyọ ẹnìkan wọn kò sì sùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tòògbé. Àmùrè ẹnìkankan kò tú, bẹ́ẹ̀ ni okùn bàtà ẹnìkankan kò já.


Nígbà tí ọba Babiloni gbọ́ ìró wọn, ọwọ́ rẹ̀ rọ, ìrora sì mú un bíi ti obinrin tí ń rọbí.


Bí wọ́n bá bi ọ́ pé kí ló dé tí o fi ń mí ìmí ẹ̀dùn, sọ fún wọn pé nítorí ìròyìn tí o gbọ́ ni. Nígbà tí ó bá ṣẹlẹ̀, ọkàn gbogbo eniyan yóo dàrú, ọwọ́ wọn yóo rọ ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá wọn, ẹsẹ̀ wọn kò ní ranlẹ̀ mọ́. Wò ó! Yóo ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀, n óo sì mú un ṣẹ. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Ọwọ́ gbogbo wọ́n yóo rọ; orúnkún wọn kò ní lágbára.


Ní ọdún keji tí Nebukadinesari gun orí oyè, ó lá àwọn àlá kan; àlá náà bà á lẹ́rù tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi lè sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà.


Inú bá bí Nebukadinesari gidigidi, ojú rẹ̀ yipada sí Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá iná, kí ó gbóná ní ìlọ́po meje ju bíí tií máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ.


Ọkàn Daniẹli, tí wọn ń pè ní Beteṣasari, pòrúúruù fún ìgbà díẹ̀, ẹ̀rù sì bà á. Ọba bá sọ fún un pé: “Má jẹ́ kí àlá yìí ati ìtumọ̀ rẹ̀ bà ọ́ lẹ́rù.” Beteṣasari dáhùn pé, “olúwa mi, kí àlá yìí ṣẹ mọ́ àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ lára, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì dà lé àwọn ọ̀tá rẹ lórí.


Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù. Èrò ọkàn mi ati ìran tí mo rí lórí ibùsùn mi kó ìdààmú bá mi.


Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sí ara ògiri ààfin níbi tí iná fìtílà tan ìmọ́lẹ̀ sí, ọba rí ọwọ́ náà, bí ó ti ń kọ̀wé.


“Òpin ọ̀rọ̀ nípa ìran náà nìyí. Ẹ̀rù èrò ọkàn mi bà mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí ojú mi yipada, ṣugbọn inú ara mi ni mo mọ ọ̀rọ̀ náà sí.”


A ti pa Ninefe run! Ó ti dahoro! Ọkàn àwọn eniyan ti dàrú, orúnkún wọn ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, ìrora dé bá ọpọlọpọ, gbogbo ojú wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.


Nítorí náà ẹ gbé ọwọ́ yín tí kò lágbára sókè, ẹ mú kí eékún yín tí ń gbọ̀n di alágbára;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan