Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:23 - Yoruba Bible

23 Ò ń gbéraga sí Ọlọrun ọ̀run. O ranṣẹ lọ kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun wá siwaju rẹ. Ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ayaba ati àwọn obinrin rẹ, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí waini. Ẹ sì ń yin àwọn oriṣa fadaka, ti wúrà, ti idẹ, ti irin, ti igi ati ti òkúta. Wọn kò ríran wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. O kò yin Ọlọrun tí ẹ̀mí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ lógo, ẹni tí ó mọ gbogbo ọ̀nà rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

23 Ṣugbọn iwọ gbé ara rẹ ga si Oluwa ọrun, nwọn si ti mu ohun-elo ile rẹ̀ wá siwaju rẹ, iwọ ati awọn ijoye rẹ, ati awọn aya rẹ, ati awọn àle rẹ si ti nmu ọti-waini ninu wọn; iwọ si ti nkọrin iyìn si oriṣa fadaka, ati ti wura, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta, awọn ti kò riran, ti kò gbọran, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀: ṣugbọn Ọlọrun na, lọwọ ẹniti ẹmi rẹ wà, ati ti ẹniti gbogbo ọ̀na rẹ iṣe on ni iwọ kò bu ọlá fun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú ohun èlò inú tẹmpili rẹ̀ wá sí iwájú rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì. Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́rọ̀ tàbí ní òye nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:23
47 Iomraidhean Croise  

Ó súre fún Abramu, ó ní: “Kí Ọlọrun Ọ̀gá Ògo, tí ó dá ọ̀run ati ayé bukun Abramu.


Nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun bù ninu erùpẹ̀ ilẹ̀, ó fi mọ eniyan. Ó mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, eniyan sì di ẹ̀dá alààyè.


Nisinsinyii, ìwọ Amasaya, nítorí pé o ti ṣẹgun Edomu, ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga. Jẹ́ kí ògo rẹ yìí tẹ́ ọ lọ́rùn, kí ló dé tí o fi fẹ́ dá ìjàngbọ̀n sílẹ̀ sí ìparun ara rẹ ati ti Juda?”


Ọwọ́ rẹ̀ ni ìyè gbogbo ẹ̀dá wà, ati ẹ̀mí gbogbo eniyan.


Ṣebí Ọlọrun mọ ọ̀nà mi, ó sì mọ ìrìn mi.


Bí o bá fojú pamọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n, bí o bá gba ẹ̀mí wọn, wọn á kú, wọn á sì pada di erùpẹ̀.


OLUWA ló ni ọ̀run, ṣugbọn ó fi ayé fún àwọn eniyan.


O yẹ ìrìn ẹsẹ̀ mi ati àbọ̀sinmi mi wò; gbogbo ọ̀nà mi ni o sì mọ̀.


Bí ẹ̀mí wọn bá ti bọ́, wọn á pada di erùpẹ̀, ní ọjọ́ náà sì ni èrò inú wọn óo di ègbé.


OLUWA ní ń tọ́ ìṣísẹ̀ ẹni, eniyan kò lè ní òye ọ̀nà ara rẹ̀.


N óo fìyà jẹ ayé nítorí iṣẹ́ ibi rẹ̀, n óo sì jẹ àwọn ìkà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo fòpin sí àṣejù àwọn onigbeeraga, n óo rẹ ìgbéraga àwọn tí kò lójú àánú sílẹ̀.


Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘N óo gòkè dé ọ̀run, n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run; n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan, ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré.


Nítorí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀, tí yóo dojú ìjà kọ àwọn agbéraga, ati àwọn ọlọ́kàn gíga, ati gbogbo nǹkan tí à ń gbéga.


OLUWA ní: “Ó yá tí n óo dìde, ó yá mi wàyí, n óo gbéra nílẹ̀. Àsìkò tó tí a óo gbé mi ga.


ati pé wọ́n ju oriṣa wọn sinu iná, nítorí pé wọn kì í ṣe Ọlọrun. Iṣẹ́ ọwọ́ eniyan ni wọ́n, tí wọ́n fi igi ati òkúta ṣe, nítorí náà ni wọ́n ṣe lè pa wọ́n run.


Ta ni ò ń sọ̀rọ̀ aṣa sí, tí ò ń fí ń ṣe ẹlẹ́yà? Ta ni ò ń ṣíjú wò pẹlu ìgbéraga? Ṣé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni o ṣe irú èyí sí?


Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA Ọlọrun sọ; ẹni tí ó dá ojú ọ̀run tí ó sì ta á bí aṣọ, tí ó tẹ ayé, ati àwọn ohun tí ń hù jáde láti inú rẹ̀; ẹni tí ó fi èémí sinu àwọn eniyan tí ń gbé orí ilẹ̀; tí ó sì fi ẹ̀mí fún àwọn tí ó ń rìn lórí rẹ̀.


OLUWA, mo mọ̀ pé ọ̀nà ẹ̀dá kò sí ní ọwọ́ ara rẹ̀. Kò sí ní ìkáwọ́ ẹni tí ń rìn láti tọ́ ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.


OLUWA ní, “Ẹ rọ Moabu lọ́tí yó, nítorí pé ó gbéraga sí OLUWA; kí ó lè máa yíràá ninu èébì rẹ̀, a óo sì fi òun náà ṣẹ̀sín.


(Ẹ gbọ́ ariwo bí àwọn eniyan tí ń sá àsálà kúrò ní ilẹ̀ Babiloni, wá sí Sioni, láti wá ròyìn ìgbẹ̀san Ọlọrun wa, ẹ̀san tẹmpili rẹ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀.)


“Ẹ pe àwọn tafàtafà jọ, kí wọn dojú kọ Babiloni; kí gbogbo àwọn tí wọn ń tafà pàgọ́ yí i ká, kí wọn má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni sá àsálà. Ẹ san án fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ẹ ṣe sí i bí ó ti ṣe sí àwọn ẹlòmíràn; nítorí pé ó ṣe àfojúdi sí OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli.


Ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga nítorí pé o lẹ́wà, o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́ nítorí ògo rẹ. Mo bì ọ́ lulẹ̀, mo sọ ọ́ di ìran wíwò fún àwọn ọba.


“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún ọba Tire pé OLUWA ní, ‘Nítorí pé ìgbéraga kún ọkàn rẹ, o sì ti sọ ara rẹ di oriṣa, o sọ pé o jókòó ní ibùjókòó àwọn oriṣa láàrin òkun; bẹ́ẹ̀ sì ni eniyan ni ọ́, o kì í ṣe oriṣa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ò ń rò pé o gbọ́n bí àwọn oriṣa,


O ti ní àníkún ọrọ̀ nítorí ọgbọ́n rẹ ninu òwò ṣíṣe, ìgbéraga sì ti kún ọkàn rẹ nítorí ọrọ̀ rẹ.’


“Nítorí pé ó ga sókè fíofío, góńgó orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu lójú ọ̀run, ọkàn rẹ̀ sì kún fún ìgbéraga nítorí gíga rẹ̀.


Ọba Ijipti óo máa gbéraga nítorí ìṣẹ́gun rẹ̀ lórí ọpọlọpọ ogun yìí, yóo sì pa ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun, ṣugbọn kò ní borí.


“Ẹ gbọ́, èmi Nebukadinesari, fi ìyìn, ògo, ati ọlá fún ọba ọ̀run. Nítorí pé gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ pé, ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ó sì lè rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.”


Ó gbé ara rẹ̀ ga, títí dé ọ̀dọ̀ olórí àwọn ogun ọ̀run. Ó gbé ẹbọ sísun ojoojumọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì gba ibi mímọ́ rẹ̀.


Wò ó! Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò ṣe déédéé ninu OLUWA yóo ṣègbé; ṣugbọn olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.”


bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí kò ní, tí a óo sọ pé kí eniyan fún un, nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó ń fún gbogbo eniyan ní ẹ̀mí, èémí ati ohun gbogbo.


Nítorí náà nípa oúnjẹ tí a fi rúbọ fún oriṣa, a mọ̀ pé oriṣa kò jẹ́ nǹkankan ninu ayé. Ati pé kò sí Ọlọrun mìíràn àfi ọ̀kan ṣoṣo.


Kí ó má jẹ́ ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onigbagbọ, kí ó má baà gbéraga, kí ó wá bọ́ sọ́wọ́ Satani.


Kò sí ẹ̀dá kan tí ó lè fara pamọ́ níwájú rẹ̀. Gbogbo nǹkan ṣípayá kedere níwájú Ọlọrun, ẹni tí a óo jíyìn iṣẹ́ wa fún.


Àwọn eniyan tí ó kù, tí wọn kò kú ninu àjàkálẹ̀ àrùn yìí kò ronupiwada. Wọn kò kọ iṣẹ́ ọwọ́ wọn tí wọn ń bọ sílẹ̀. Ṣugbọn wọ́n tún ń sin àwọn ẹ̀mí burúkú, ati oriṣa wúrà, ti fadaka, ti idẹ, ti òkúta, ati ti igi. Àwọn oriṣa tí kò lè ríran, wọn kò lè gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lè rìn.


Ní ọjọ́ kan, àwọn ọba Filistini kó ara wọn jọ láti rú ẹbọ ńlá kan sí Dagoni, oriṣa wọn, ati láti ṣe àríyá pé oriṣa wọn ni ó fi Samsoni ọ̀tá wọn lé wọn lọ́wọ́.


Dafidi bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọkunrin náà pé, “Kí ni ọba ṣe ìlérí pé òun ó fún ẹni tí ó bá pa Filistini yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Israẹli? Ta ni aláìkọlà Filistini yìí tí ń pẹ̀gàn àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè?”


Èmi iranṣẹ rẹ yìí ti pa àwọn kinniun ati àwọn ẹranko beari rí, aláìkọlà Filistini yìí yóo sì dàbí ọ̀kan ninu wọn, nítorí pé, ó ti pe àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè níjà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan