Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:22 - Yoruba Bible

22 “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ ọmọ rẹ̀ Beṣasari, o kọ̀, o kò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Ati iwọ Belṣassari, ọmọ rẹ̀, iwọ kò rẹ̀ ọkàn rẹ silẹ, bi iwọ si tilẹ ti mọ̀ gbogbo nkan wọnyi;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 “Ṣùgbọ́n ìwọ ọmọ rẹ̀, Belṣassari, ìwọ kò rẹ ara à rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ mọ nǹkan wọ̀nyí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:22
17 Iomraidhean Croise  

Kò fi ìgbà kankan ronupiwada bí baba rẹ̀ ti ṣe níwájú OLUWA. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń dá kún ẹ̀ṣẹ̀.


Nítorí náà, Mose ati Aaroni lọ, wọ́n sì wí fún Farao pé, “OLUWA Ọlọrun àwọn Heberu ní kí á bèèrè lọ́wọ́ rẹ pé, yóo ti pẹ́ tó tí o óo fi kọ̀ láti rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú òun Ọlọrun? Ó ní, kí o jẹ́ kí àwọn eniyan òun lọ kí wọ́n lè sin òun.


Nítorí náà, ẹni tí ó bá mọ rere í ṣe tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń gbà.


Ohun tí ó ṣe burú lójú OLUWA Ọlọrun rẹ̀, kò rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ níwájú wolii Jeremaya ẹni tí Ọlọrun rán sí i láti bá a sọ̀rọ̀.


Ṣugbọn oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fi fúnni tóbi ju èyí lọ. Nítorí èyí ni Ìwé Mímọ́ ṣe sọ pé, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn ó fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.”


Bí ẹ bá mọ nǹkan wọnyi, ẹ óo láyọ̀ bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.


“Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó bá mọ ohun tí oluwa rẹ̀ fẹ́, ṣugbọn tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ìfẹ́ oluwa rẹ̀ yóo jìyà pupọ.


Nítorí Johanu wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, ṣugbọn ẹ kò gbà á gbọ́. Ṣugbọn àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́. Lẹ́yìn tí ẹ rí èyí, ẹ kò ronupiwada kí ẹ gbà á gbọ́.”


Nítorí Johanu sọ fún Hẹrọdu pé kò tọ́ fún un láti fi Hẹrọdiasi ṣaya.


“Kabiyesi, Ọlọrun tí ó ga jùlọ fún Nebukadinesari, baba rẹ ní ìjọba, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó fún un ní ògo ati ọlá.


Bí a bá ṣàánú ẹni ibi, kò ní kọ́ láti ṣe rere. Yóo máa ṣe ibi ní ilẹ̀ àwọn olódodo, kò sì ní rí ọlá ńlá OLUWA.


N óo máa sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba, ojú kò sì ní tì mí.


N óo fìyà jẹ ayé nítorí iṣẹ́ ibi rẹ̀, n óo sì jẹ àwọn ìkà níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. N óo fòpin sí àṣejù àwọn onigbeeraga, n óo rẹ ìgbéraga àwọn tí kò lójú àánú sílẹ̀.


Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘N óo gòkè dé ọ̀run, n óo gbé ìtẹ́ mi kọjá àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run; n óo jókòó lórí òkè àpéjọ àwọn eniyan, ní ìhà àríwá ní ọ̀nà jíjìn réré.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan