Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:18 - Yoruba Bible

18 “Kabiyesi, Ọlọrun tí ó ga jùlọ fún Nebukadinesari, baba rẹ ní ìjọba, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó fún un ní ògo ati ọlá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Iwọ ọba! Ọlọrun Ọga-ogo fi ijọba, ati ọlanla, ati ogo, ati ọlá fun Nebukadnessari, baba rẹ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 “Ìwọ ọba, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo fún Nebukadnessari baba rẹ ní ìjọba, títóbi ògo àti ọlá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:18
25 Iomraidhean Croise  

Ó bá a sọ̀rọ̀ rere, ó sì fi sí ipò tí ó ga ju ti gbogbo àwọn ọba tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ ní Babiloni lọ.


Nítorí pé ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni OLUWA, Ọ̀gá Ògo, Ọba ńlá lórí gbogbo ayé.


N óo fi ọpẹ́ tí ó yẹ fún OLUWA nítorí òdodo rẹ̀, n óo fi orin ìyìn kí OLUWA, Ọ̀gá Ògo.


N óo yọ̀, inú mi yóo sì máa dùn nítorí rẹ; n óo kọ orin ìyìn orúkọ rẹ, ìwọ Ọ̀gá-Ògo jùlọ.


Ṣugbọn ẹni àgbéga títí lae ni ọ́, OLUWA.


n óo ranṣẹ lọ kó gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àríwá wá. N óo ranṣẹ sí Nebukadinesari ọba Babiloni, iranṣẹ mi, n óo jẹ́ kí wọn wá dó ti ilẹ̀ yìí, ati àwọn tí ń gbé ibẹ̀. Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó wà ní agbègbè ilẹ̀ yìí ni n óo parun patapata, tí n óo sọ di àríbẹ̀rù, ati àrípòṣé, ati ohun ẹ̀gàn títí lae.


òun ni òun fi agbára ńlá òun dá ayé: ati eniyan ati ẹranko tí wọ́n wà lórí ilẹ̀; ẹni tí ó bá tọ́ lójú òun ni òun óo sì fi wọ́n fún.


Gbogbo orílẹ̀-èdè ni yóo máa ṣe ẹrú òun ati ọmọ rẹ̀, ati ọmọ ọmọ rẹ̀, títí àkókò tí ilẹ̀ òun pàápàá yóo fi tó, tí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ati àwọn ọba ńláńlá yóo sì kó o lẹ́rú.”


kí á máa já ẹ̀tọ́ olódodo gbà lọ́wọ́ rẹ̀ níwájú Ọ̀gá Ògo,


Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògo ni rere ati burúkú ti ń jáde?


N óo fi lé ẹni tí ó lágbára jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, yóo sì ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo lé e jáde.


Láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ ni ìdájọ́ yìí ti wá, ìpinnu náà jẹ́ ti àwọn Ẹni Mímọ́; kí gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù ú níí máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́, pàápàá láàrin àwọn ẹni tí ó rẹlẹ̀ jùlọ.’


Ọkàn Daniẹli, tí wọn ń pè ní Beteṣasari, pòrúúruù fún ìgbà díẹ̀, ẹ̀rù sì bà á. Ọba bá sọ fún un pé: “Má jẹ́ kí àlá yìí ati ìtumọ̀ rẹ̀ bà ọ́ lẹ́rù.” Beteṣasari dáhùn pé, “olúwa mi, kí àlá yìí ṣẹ mọ́ àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ lára, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì dà lé àwọn ọ̀tá rẹ lórí.


Ó tọ́ lójú mi láti fi àmì ati iṣẹ́ ìyanu, tí Ọlọrun tí ó ga jùlọ ṣe fún mi, hàn.


a óo lé ọ kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo máa bá àwọn ẹranko gbé, o óo sì máa jẹ koríko bíi mààlúù fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé, Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ati pé ẹni tí ó bá wù ú ní í máa gbé e lé lọ́wọ́.”


Nebukadinesari ní, “Lẹ́yìn ọdún meje náà, èmi, Nebukadinesari, gbé ojú sí òkè ọ̀run, iyè mi pada bọ̀ sípò. Mo yin Ẹni Gíga Jùlọ, mo fi ọlá ati ògo fún Ẹni Ayérayé. “Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ̀ láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀, àní, láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀.


A lé e kúrò láàrin àwọn ọmọ eniyan, ọkàn rẹ̀ dàbí ti ẹranko. Ó ń bá àwọn ẹranko gbé inú igbó. Ó ń jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì sì sẹ̀ sí i lára, títí ó fi mọ̀ pé Ọlọrun tí ó ga jùlọ, ni ó ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, tí ó sì ń gbé e fún ẹni tí ó bá wù ú.


Ọlọrun mi ti rán angẹli rẹ̀, ó ti dí àwọn kinniun lẹ́nu, wọn kò sì pa mí lára. Nítorí pé n kò jẹ̀bi níwájú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì ṣe nǹkan burúkú sí ìwọ ọba.”


Kabiyesi, bí mo ti ń lọ lọ́nà lọ́sàn-án gangan, mo rí ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run tí ó mọ́lẹ̀ ju ti oòrùn lọ, tí ó tàn yí èmi ati àwọn tí ń bá mi lọ ká.


“Nítorí náà, Agiripa Ọba Aláyélúwà, n kò ṣe àìgbọràn sí ìran tí ó ti ọ̀run wá.


“Bẹ́ẹ̀ ni Ọba tí ó ga jùlọ kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́. Gẹ́gẹ́ bí wolii nì ti sọ:


Nígbà tí Ọlọrun ọ̀gá ògo pín ilẹ̀ ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè, ó ṣètò ibi tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan yóo máa gbé, gẹ́gẹ́ bí ìdílé kọ̀ọ̀kan láàrin àwọn ọmọ Israẹli.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan