Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:16 - Yoruba Bible

16 Mo ti gbọ́ nípa rẹ pé o lè túmọ̀ ohun ìjìnlẹ̀, o sì lè yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú; nisinsinyii, bí o bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, wọn óo wọ̀ ọ́ ní aṣọ elése àlùkò, wọn óo sì fi ẹ̀gbà wúrà sí ọ lọ́rùn, o óo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ní ìjọba mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Emi si gburo rẹ pe, iwọ le ṣe itumọ, iwọ si le tu ọ̀rọ ti o diju: njẹ nisisiyi, bi iwọ ba le ka iwe na, ti iwọ ba si le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, a o wọ̀ ọ li aṣọ ododó, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a o si fi ọ jẹ olori ẹkẹta ni ijọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ wí pé, ìwọ lè sọ ìtumọ̀, àti wí pé o lè yanjú àwọn ìṣòro tó lágbára. Tí o bá lè ka àkọsílẹ̀ ìwé yìí kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, a ó fi aṣọ elése àlùkò wọ̀ ọ́ pẹ̀lú ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọ lọ́rùn, a ó sì fi ọ́ ṣe olórí kẹta ní ìjọba mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:16
9 Iomraidhean Croise  

Wọ́n dá a lóhùn pé, “A lá àlá kan ni, a kò sì rí ẹni bá wa túmọ̀ rẹ̀.” Josẹfu dá wọn lóhùn, ó ní, “Ṣebí Ọlọrun ni ó ni ìtumọ̀ àlá? Ẹ rọ́ àlá náà fún mi.”


Farao sọ fún un pé, “Mo lá àlá kan, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè túmọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá sọ fún mi pé, bí o bá gbọ́ àlá, o óo lè túmọ̀ rẹ̀.”


Farao bá bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó fi bọ Josẹfu lọ́wọ́, ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun olówó iyebíye, ó sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn.


Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni.


Ṣugbọn bí ẹ bá rọ́ àlá náà, tí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹ óo gba ẹ̀bùn, ìdálọ́lá ati ẹ̀yẹ ńlá, nítorí náà ẹ rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”


Beṣasari bá pàṣẹ, pé kí wọ́n gbé ẹ̀wù elése àlùkò, ti àwọn olóyè, wọ Daniẹli, kí wọ́n sì fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn. Wọ́n kéde ká gbogbo ìjọba pé Daniẹli ni igbá kẹta ní ìjọba.


Ó kígbe sókè pé kí wọ́n tètè lọ pe àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea ati àwọn awòràwọ̀ wá. Nígbà tí wọ́n dé, ọba sọ fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka ohun tí wọ́n kọ sára ògiri yìí, tí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fi aṣọ elése àlùkò dá a lọ́lá, n óo ní kí wọ́n fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, yóo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ninu ìjọba mi.”


Ó yan àwọn mẹta láti máa ṣe àbojútó gbogbo wọn, Daniẹli sì jẹ́ ọ̀kan ninu wọn. Àwọn mẹta wọnyi ni àwọn ọgọfa (120) gomina náà yóo máa jábọ̀ fún.


Nígbà tí Simoni rí i pé ọwọ́ tí àwọn aposteli gbé lé wọn ni ó mú kí wọ́n rí Ẹ̀mí gbà, ó fi owó lọ̀ wọ́n.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan