Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:13 - Yoruba Bible

13 Wọ́n bá mú Daniẹli wá siwaju ọba. Ọba bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ẹrú, tí baba mi kó wá láti ilẹ̀ Juda?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Nigbana ni a mu Danieli wá siwaju ọba. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Iwọ ni Danieli nì, ti iṣe ti inu awọn ọmọ igbekun Juda! awọn ẹniti ọba, baba mi kó lati ilẹ Juda wá?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Nígbà náà ni a mú Daniẹli wá síwájú ọba, ọba sì sọ fún un wí pé, “Ṣé ìwọ ni Daniẹli, ọ̀kan lára àwọn tí baba mi mú ní ìgbèkùn láti Juda!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:13
20 Iomraidhean Croise  

Àwọn tí wọ́n pada ti oko ẹrú dé gba ìmọ̀ràn yìí. Nítorí náà, Ẹsira alufaa yan àwọn olórí ninu ìdílé wọn, wọ́n kọ orúkọ wọn sílẹ̀. Ní ọjọ́ kinni oṣù kẹwaa, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìwádìí lórí ọ̀rọ̀ yìí.


Wọ́n kéde jákèjádò Juda ati Jerusalẹmu pé kí gbogbo àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé péjọ sí Jerusalẹmu.


Nígbà ti àwọn ọ̀tá Juda ati ti Bẹnjamini gbọ́ pé àwọn tí wọ́n ti ìgbèkùn dé ti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé OLUWA Ọlọrun Israẹli,


Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli: àwọn alufaa, àwọn ẹ̀yà Lefi ati àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú pada dé bá fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ tẹmpili náà.


Ní ọdún kẹta ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, Nebukadinesari ọba Babiloni wá gbógun ti Jerusalẹmu, ó sì dótì í.


OLUWA jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ Jehoiakimu ọba Juda. Nebukadinesari kó ninu àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun lọ sí ilẹ̀ Ṣinari, ó sì kó wọn sinu ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé oriṣa rẹ̀.


Daniẹli sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kinni ìjọba Kirusi.


Daniẹli, ati Hananaya, ati Miṣaeli ati Asaraya wà lára àwọn tí wọ́n ṣà ninu ẹ̀yà Juda.


Arioku bá mú Daniẹli lọ sí ọ̀dọ̀ ọba kíákíá. Ó sọ fún ọba pé: “Kabiyesi, mo ti rí ọkunrin kan ninu àwọn tí wọ́n kó lẹ́rú wá láti Juda, tí ó le túmọ̀ àlá náà fún ọba.”


Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni.


Ẹnìkan ń bẹ ní ìjọba rẹ tí ó ní ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ninu. Ní àkókò baba rẹ, a rí ìmọ́lẹ̀, ìmọ̀, ati ọgbọ́n bíi ti Ọlọrun ninu rẹ̀. Òun ni baba rẹ, Nebukadinesari ọba, fi ṣe olórí gbogbo àwọn pidánpidán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn Kalidea ati àwọn awòràwọ̀;


Mo ti gbọ́ pé ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ń bẹ ninu rẹ; ati pé o ní ìmọ̀, òye, ati ọgbọ́n tí kò lẹ́gbẹ́.


“Kabiyesi, Ọlọrun tí ó ga jùlọ fún Nebukadinesari, baba rẹ ní ìjọba, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó fún un ní ògo ati ọlá.


Nígbà tí ó tọ́ ọtí náà wò, ó pàṣẹ pé kí wọn kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí Nebukadinesari, baba rẹ̀, kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, kí òun, ati àwọn ìjòyè òun, àwọn ayaba ati àwọn obinrin òun lè máa fi wọ́n mu ọtí.


Wọ́n bá sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ìgbèkùn Juda kò kà ọ́ sí, kò sì pa òfin rẹ mọ́. Ṣugbọn ìgbà mẹta lóòjọ́ níí máa gbadura.”


Ní ọdún kẹta tí Beṣasari jọba ni èmi Daniẹli rí ìran kan lẹ́yìn ti àkọ́kọ́.


Àárẹ̀ mú èmi Daniẹli, mo sì ṣàìsàn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Nígbà tó yá, mo bá tún dìde, mò ń bá iṣẹ́ tí ọba yàn mí sí lọ, ṣugbọn ìran náà dẹ́rù bà mí, kò sì yé mi.


Lẹ́yìn èyí, Jesu ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Galili nítorí kò fẹ́ máa káàkiri ilẹ̀ Judia mọ́, nítorí àwọn Juu ń wá ọ̀nà láti pa á.


Àwọn arakunrin Jesu sọ fún un pé, “Kúrò níhìn-ín kí o lọ sí Judia, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ lè rí iṣẹ́ tí ò ń ṣe,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan