Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:10 - Yoruba Bible

10 Nígbà tí ayaba gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọba ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ó wọ inú gbọ̀ngàn àsè náà, ó sọ fún ọba pé, “Kabiyesi, kí ọba kí ó pẹ́, má jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí dààmú rẹ tabi kí ó mú kí ojú rẹ fàro.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Nitorina ni ayaba ṣe wọ ile-àse wá, nitori ọ̀ran ọba, ati ti awọn ijoye rẹ̀; ayaba dahùn o si wipe, Ki ọba ki o pẹ́: má ṣe jẹ ki ìro-inu rẹ ki o dãmu rẹ, má si jẹ ki oju rẹ ki o yipada.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nígbà tí ayaba gbọ́ ohùn ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó wá ilé àsè wá. Ó wí pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Má ṣe jẹ́ kí inú rẹ bàjẹ́, má sì ṣe jẹ́ kí ojú u rẹ fàro.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:10
10 Iomraidhean Croise  

Batiṣeba wólẹ̀ níwájú ọba, ó dojúbolẹ̀, ó ní, “Kabiyesi, oluwa mi, kí ẹ̀mí ọba ó gùn.”


Ẹ̀yin òpùrọ́ ati ẹlẹ́tàn wọnyi, ẹ̀yin oníṣègùn tí ẹ kò lè wonisàn.


Nítorí náà, kí ni ìsọkúsọ tí ẹ lè fi tù mí ninu? Kò sóhun tó kù ninu ọ̀rọ̀ yín, tó ju irọ́ lọ.”


Àwọn ará Kalidea bá dá ọba lóhùn pé, “Kí ọba pẹ́! Rọ́ àlá rẹ fún àwa iranṣẹ rẹ, a óo sì túmọ̀ rẹ̀.”


“Kí ọba kí ó pẹ́!


Ojú ọba yipada, ẹ̀rù bà á, ara rẹ̀ ń gbọ̀n, orúnkún rẹ̀ sì ń lu ara wọn.


Daniẹli dáhùn pé, “Kabiyesi, kí ọba pẹ́,


Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n wí fún un pé “Dariusi ọba, kí ọba pẹ́,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan