Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 5:1 - Yoruba Bible

1 Ní ọjọ́ kan, Beṣasari ọba, se àsè ńlá kan fún ẹgbẹrun (1,000) ninu àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì ń mu ọtí níwájú wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 BELṢASSARI, ọba se àse nla fun ẹgbẹrun awọn ijoye rẹ̀, o si nmu ọti-waini niwaju awọn ẹgbẹrun na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Belṣassari, ọba ṣe àsè ńlá fún ẹgbẹ̀rún (1,000) kan nínú àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó sì mu wáìnì pẹ̀lú u wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 5:1
11 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ kẹta tíí ṣe ọjọ́ ìbí Farao, ọba se àsè ńlá fún gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì mú agbọ́tí rẹ̀ ati alásè rẹ̀ jáde sí ààrin àwọn iranṣẹ rẹ̀.


ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún àwọn ìjòyè, ati àwọn olórí, àwọn òṣìṣẹ́, ati àwọn olórí ogun Pasia ati ti Media, àwọn eniyan pataki pataki tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn gomina agbègbè rẹ̀.


Ní ọjọ́ náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun fi ìpè sóde pé, kí ẹ máa sọkún, kí ẹ máa ṣọ̀fọ̀, kí ẹ fá orí yín, kí ẹ sì fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora.


OLUWA àwọn ọmọ ogun ti fi tó mi létí pé: “A kò ní dárí ẹ̀ṣẹ̀ yìí jì yín títí tí ẹ óo fi kú.”


OLUWA ní, “Idà ni yóo pa àwọn ará Kalidea, idà ni yóo pa àwọn ará Babiloni, ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn amòye wọn!


Nígbà tí ara wọn bá gbóná, n óo se àsè kan fún wọn. N óo rọ wọ́n lọ́tí yó, títí tí wọn óo fi máa yọ ayọ̀ ẹ̀sín, tí wọn óo sì sùn lọ títí ayé. Wọn óo sùn, wọn kò sì ní jí mọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.


N óo jẹ́ kí àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ mu ọtí ní àmuyó, pẹlu àwọn gomina rẹ̀, àwọn ọ̀gágun rẹ̀, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Wọn yóo sun oorun àsùnrayè, wọn kò sì ní jí mọ́ laelae. Bẹ́ẹ̀ ni èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ.


Ní alẹ́ ọjọ́ náà gan-an ni wọ́n pa Beṣasari, ọba àwọn ará Kalidea.


Wọn yóo jóná bí igbó ẹlẹ́gùn-ún tí ó dí, àní bíi koríko gbígbẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan