Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:9 - Yoruba Bible

9 Beteṣasari, olórí gbogbo àwọn pidánpidán, mo mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ, ati pé o mọ gbogbo àṣírí. Gbọ́ àlá mi kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Belteṣassari, olori awọn amoye, nitoriti mo mọ̀ pe ẹmi Ọlọrun mimọ mbẹ ninu rẹ, kò si si aṣiri kan ti o ṣoro fun ọ, sọ iran alá ti mo lá fun mi, ati itumọ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Mo wí pé, “Belṣassari, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì ṣí àṣírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:9
18 Iomraidhean Croise  

Ó bá sọ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ǹjẹ́ a lè rí irú ọkunrin yìí, ẹni tí ẹ̀mí Ọlọrun ń gbé inú rẹ̀?”


Ẹ óo máa ronú ìnira tí ẹ ti ní pé: “Níbo ni akọ̀wé wà? Níbo ni ẹni tí ń gba owó orí wà? Níbo sì ni ẹni tí ń ka ilé ìṣọ́ wà?”


A óo fìdí rẹ múlẹ̀, ninu òdodo, o óo jìnnà sí ìnira, nítorí náà ẹ̀rù kò ní bà ọ́. O óo jìnnà sí ìpayà, nítorí kò ní súnmọ́ ọ.


Lórí òkè gíga Israẹli ni n óo gbìn ín sí, kí ó lè yọ ẹ̀ka, kí ó so, kí ó sì di igi Kedari ńlá. Oríṣìíríṣìí ẹranko ìgbẹ́ ni yóo máa gbé abẹ́ rẹ̀. Oríṣìíríṣìí ẹyẹ yóo pa ìtẹ́ sí abẹ́ òjìji ẹ̀ka rẹ̀.


nítòótọ́, o gbọ́n ju Daniẹli lọ, kò sì sí ohun àṣírí kan tí ó ṣú ọ lójú.


Ninu gbogbo ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí ọba bi wọ́n, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn pidánpidán ati àwọn aláfọ̀ṣẹ tí ó wà ní ìjọba rẹ̀ lọ.


Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.”


Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni.


“Ìran tí èmi Nebukadinesari rí nìyí. Ìwọ Beteṣasari, sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ìjọba mi kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣugbọn o lè ṣe é, nítorí pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ.”


Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù. Èrò ọkàn mi ati ìran tí mo rí lórí ibùsùn mi kó ìdààmú bá mi.


Lẹ́yìn gbogbo wọn patapata ni Daniẹli dé, tí a sọ ní Beteṣasari, orúkọ oriṣa mi, Daniẹli yìí ní ẹ̀mí Ọlọrun ninu. Mo rọ́ àlá mi fún un, mo ní:


Ẹnìkan ń bẹ ní ìjọba rẹ tí ó ní ẹ̀mí Ọlọrun Mímọ́ ninu. Ní àkókò baba rẹ, a rí ìmọ́lẹ̀, ìmọ̀, ati ọgbọ́n bíi ti Ọlọrun ninu rẹ̀. Òun ni baba rẹ, Nebukadinesari ọba, fi ṣe olórí gbogbo àwọn pidánpidán, àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn Kalidea ati àwọn awòràwọ̀;


A gbé! Ta ni lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn oriṣa tí ó lágbára wọnyi? Àwọn ni wọ́n pa àwọn ará Ijipti ní ìpakúpa ninu aṣálẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan