Daniẹli 4:7 - Yoruba Bible7 Gbogbo àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea, ati àwọn awòràwọ̀ bá péjọ siwaju mi; mo rọ́ àlá náà fún wọn, ṣugbọn wọn kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Nigbana ni awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá siwaju mi: emi si rọ́ alá na fun wọn, ṣugbọn nwọn kò le fi ìtumọ rẹ̀ hàn fun mi. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Nígbà tí àwọn apidán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi. Faic an caibideil |
Ó kígbe sókè pé kí wọ́n tètè lọ pe àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea ati àwọn awòràwọ̀ wá. Nígbà tí wọ́n dé, ọba sọ fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka ohun tí wọ́n kọ sára ògiri yìí, tí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fi aṣọ elése àlùkò dá a lọ́lá, n óo ní kí wọ́n fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, yóo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ninu ìjọba mi.”