Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:4 - Yoruba Bible

4 “Èmi, Nebukadinesari wà ninu ìdẹ̀ra ní ààfin mi, nǹkan sì ń dára fún mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Emi Nebukadnessari wà li alafia ni ile mi, mo si ngbilẹ li ãfin mi:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Èmi Nebukadnessari wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:4
13 Iomraidhean Croise  

Wọn á máa sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á mu waini, ẹ jẹ́ kí á mu ọtí líle ní àmuyó, bí òní ṣe rí ni ọ̀la yóo rí, yóo dùn tayọ.”


OLUWA ní, “Láti ìgbà èwe Moabu ni ó ti ń gbé pẹlu ìrọ̀rùn, kò tíì lọ sí ìgbèkùn rí. Nítorí náà ó silẹ̀ bí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ọtí. A kò máa dà á kiri láti inú ìgò kan sí òmíràn. Adùn rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀, òórùn rẹ̀ kò sì tíì yipada.


Ọkàn rẹ kún fún ìgbéraga nítorí pé o lẹ́wà, o ba ọgbọ́n rẹ jẹ́ nítorí ògo rẹ. Mo bì ọ́ lulẹ̀, mo sọ ọ́ di ìran wíwò fún àwọn ọba.


OLUWA Ọlọrun ní: Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Farao, ọba Ijipti, Ìwọ diragoni ńlá tí o wà láàrin odò rẹ; tí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili mi; ara mi ni mo dá a fún.’


Ohun tí ọba ń bèèrè yìí le pupọ, kò sí ẹni tí ó lè ṣe é, àfi àwọn oriṣa, nítorí pé àwọn kì í ṣe ẹlẹ́ran ara.”


Ọkàn Daniẹli, tí wọn ń pè ní Beteṣasari, pòrúúruù fún ìgbà díẹ̀, ẹ̀rù sì bà á. Ọba bá sọ fún un pé: “Má jẹ́ kí àlá yìí ati ìtumọ̀ rẹ̀ bà ọ́ lẹ́rù.” Beteṣasari dáhùn pé, “olúwa mi, kí àlá yìí ṣẹ mọ́ àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ lára, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì dà lé àwọn ọ̀tá rẹ lórí.


Gbogbo àwọn amòye ọba wá, wọn kò lè ka àwọn àkọsílẹ̀ náà, wọn kò sì lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.


“Ní àkókò náà ni n óo tanná wo Jerusalẹmu fínnífínní, n óo jẹ àwọn ọkunrin tí wọ́n rò pé àwọn gbọ́n lójú ara wọn níyà, àwọn tí ń sọ ninu ọkàn wọn pé, ‘kò sí ohun tí Ọlọrun yóo ṣe.’


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan