Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:30 - Yoruba Bible

30 ó ní, “Ẹ wo bí Babiloni ti tóbi tó, ìlú tí mo fi ipá ati agbára mi kọ́, tí mo sọ di olú-ìlú fún ògo ati ọlá ńlá mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

30 Ọba si dahùn, o wipe, Ko ṣepe eyi ni Babeli nla, ti emi ti fi lile agbara mi kọ́ ni ile ijọba, ati fun ogo ọlanla mi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

30 Ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Babeli ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:30
33 Iomraidhean Croise  

Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Babeli, Ereki ati Akadi. Àwọn ìlú mẹtẹẹta yìí wà ní ilẹ̀ Babiloni.


Fún odidi ọgọsan-an (180) ọjọ́ ni ọba fi ń fi ògo ìjọba rẹ̀ hàn, pẹlu ọrọ̀ ati dúkìá rẹ̀.


Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi, OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ, ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù.


Eniyan kò lè máa gbé inú ọlá rẹ̀ títí ayé; bí ẹranko tíí kú, ni òun náà óo ku.


Wọ́n ń pẹ̀gàn eniyan, wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìlara; wọ́n sì ń fi ìgbéraga halẹ̀.


Bí ìgbéraga bá wọlé, àbùkù a tẹ̀lé e, ṣugbọn ọgbọ́n wà pẹlu àwọn onírẹ̀lẹ̀.


Ìgbéraga ní ń ṣáájú ìparun, agídí ní ń ṣáájú ìṣubú.


Ìgbéraga eniyan a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ṣugbọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn yóo gba iyì.


Babiloni, ìwọ tí o lógo jù láàrin gbogbo ìjọba ayé, ìwọ tí o jẹ́ ẹwà ati ògo àwọn ará Kalidea, yóo dàbí Sodomu ati Gomora, nígbà tí Ọlọrun pa wọ́n run.


OLUWA Ọlọrun ní: Wò ó, mo lòdì sí ọ, ìwọ Farao, ọba Ijipti, Ìwọ diragoni ńlá tí o wà láàrin odò rẹ; tí o wí pé, ‘Èmi ni mo ni odò Naili mi; ara mi ni mo dá a fún.’


Kí ó tó wí bẹ́ẹ̀ tán, ẹnìkan fọhùn láti ọ̀run, ó ní, “Nebukadinesari ọba, gbọ́ ohun tí a ti pinnu nípa rẹ: a ti gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ rẹ,


Wọn a fẹ́ wá bí ìjì, wọn a sì tún fẹ́ lọ, àwọn olubi eniyan, tí agbára wọn jẹ́ ọlọrun wọn.”


Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óo rẹ̀ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óo gbé ga.”


Ẹni tí ó pè ọ́ yóo wá tọ̀ ọ́ wá, yóo sọ fún ọ pé, ‘Fi ààyè fún ọkunrin yìí,’ Ìwọ yóo wá fi ìtìjú bẹ̀rẹ̀ sí máa wá ààyè lẹ́yìn.


Nítorí náà, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń jẹ ni, tabi pé ẹ̀ ń mu ni, ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ máa ṣe é fún ògo Ọlọrun.


Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀, bí ẹ ti ń bá ara yín lò, nítorí, “Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga, ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.”


Angẹli mìíràn tẹ̀lé ti àkọ́kọ́, ó ní, “Ó ti tú! Babiloni ìlú ńlá nnì ti tú! Ìlú tí ó fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní ọtí àgbèrè rẹ̀ mu, tí ó mú ibinu Ọlọrun wá, ó ti tú!”


Ìlú ńlá náà bá pín sí mẹta. Gbogbo ìlú àwọn orílẹ̀-èdè bá tú. Babiloni ìlú ńlá náà kò bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọrun, Ọlọrun jẹ́ kí ó mu ninu ìkorò ibinu rẹ̀.


Orúkọ àṣírí kan wà níwájú rẹ̀, ìtumọ̀ rẹ̀ ni: “Babiloni ìlú ńlá, ìyá àwọn àgbèrè ati oríṣìíríṣìí ohun ẹ̀gbin ayé.”


Wọn óo dúró ní òkèèrè nítorí ẹ̀rù tí yóo máa bà wọ́n nítorí ìrora rẹ̀. Wọn óo sọ pé, “Ó ṣe! Ó ṣe fún ọ! Ìlú ńlá, Babiloni ìlú alágbára! Nítorí ní wakati kan ni ìparun dé bá ọ.”


Ọ̀kan ninu àwọn angẹli alágbára bá gbé òkúta tí ó tóbi bí ọlọ ògì, ó jù ú sinu òkun, ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni a óo fi tagbára-tagbára sọ Babiloni ìlú ńlá náà mọ́lẹ̀ tí a kò ní rí i mọ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan