Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:3 - Yoruba Bible

3 “Iṣẹ́ rẹ̀ tóbi gan-an! Iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sì lágbára lọpọlọpọ! Títí ayérayé ni ìjọba rẹ̀, àtìrandíran rẹ̀ ni yóo sì máa jọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Ami rẹ̀ ti tobi to! agbara iṣẹ iyanu rẹ̀ ti pọ̀ to! ijọba ainipẹkun ni ijọba rẹ̀, ati agbara ijọba rẹ̀ ati irandiran ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Báwo ni ààmì rẹ̀ ti tóbi tó, Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó! Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni; ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:3
29 Iomraidhean Croise  

“Ọlọrun ni ọba, òun ló sì tó bẹ̀rù, ó ń ṣe àkóso alaafia lọ́run.


OLUWA, ìyanu ni iṣẹ́ ọwọ́ rẹ! Ọgbọ́n ni o fi dá gbogbo wọn. Ayé kún fún àwọn ẹ̀dá rẹ.


Wọ́n ṣe iṣẹ́ àmì rẹ̀ ní ilẹ̀ náà, wọ́n sì ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ ní ilẹ̀ Hamu,


Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ, yóo sì máa wà láti ìran dé ìran. Olóòótọ́ ni OLUWA ninu gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀, olóore ọ̀fẹ́ sì ni ninu gbogbo ìṣe rẹ̀.


Nípa agbára rẹ̀ ó ń jọba títí lae. Ó ń ṣọ́ àwọn orílẹ̀-èdè lójú mejeeji, kí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má gbéraga sí i.


Ẹni-ìyìn ni OLUWA Ọlọrun Israẹli, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ẹlòmíràn kò lè ṣe.


Ọ̀nà rẹ wà lójú omi òkun, ipa ọ̀nà rẹ la omi òkun ńlá já; sibẹ ẹnìkan kò rí ipa ẹsẹ̀ rẹ.


Nítorí pé o tóbi, o sì ń ṣe ohun ìyanu; ìwọ nìkan ni Ọlọrun.


Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tóbi pupọ, OLÚWA! Èrò rẹ sì jinlẹ̀ pupọ!


OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun mi. N óo gbé ọ ga: n óo yin orúkọ rẹ. Nítorí pé o ti ṣe àwọn nǹkan ìyanu, o ti ṣe àwọn ètò láti ìgbà àtijọ́, o mú wọn ṣẹ pẹlu òtítọ́.


Ọ̀dọ̀ OLUWA àwọn ọmọ ogun ni ìmọ̀ yìí ti ń wá pẹlu, ìmọ̀ràn rẹ̀ yani lẹ́nu; ọgbọ́n rẹ̀ ni ó sì ga jùlọ.


Ìjọba rẹ̀ yóo máa tóbi sí i, alaafia kò sì ní lópin ní ìjọba rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi. Yóo fìdí rẹ̀ múlẹ̀, yóo sì gbé e ró pẹlu ẹ̀tọ́ ati òdodo, láti ìgbà yìí lọ, títí ayérayé. Ìtara OLUWA àwọn ọmọ ogun ni yóo ṣe èyí


Ṣugbọn OLUWA ni Ọlọrun tòótọ́, òun ni Ọlọrun alààyè, Ọba ayérayé. Tí inú rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ síí ru ayé á mì tìtì, àwọn orílẹ̀-èdè kò lè farada ibinu rẹ̀.


Nítorí náà, ọba pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn oṣó ati àwọn ará Kalidea jọ, kí wọ́n wá rọ́ àlá òun fún òun. Gbogbo wọn sì wá siwaju ọba.


Ní àkókò àwọn ìjọba wọnyi ni Ọlọrun ọ̀run yóo gbé ìjọba kan dìde tí a kò ní lè parun, a kò sì ní fi ìjọba náà fún ẹlòmíràn. Yóo fọ́ àwọn ìjọba wọnyi túútúú, yóo pa wọ́n run, yóo sì dúró laelae.


Láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ ni ìdájọ́ yìí ti wá, ìpinnu náà jẹ́ ti àwọn Ẹni Mímọ́; kí gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù ú níí máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́, pàápàá láàrin àwọn ẹni tí ó rẹlẹ̀ jùlọ.’


A sì fún Ẹni Ayérayé ní àṣẹ, ògo ati ìjọba, pé kí gbogbo eniyan ní gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà máa sìn ín. Àṣẹ ayérayé tí kò lè yẹ̀ ni àṣẹ rẹ̀, ìjọba rẹ̀ kò sì lè parun.


A óo fi ìjọba ati àṣẹ, ati títóbi àwọn ìjọba tí ó wà láyé fún àwọn eniyan mímọ́ ti Ẹni Gíga Jùlọ, ìjọba ayérayé ni ìjọba wọn yóo jẹ́, gbogbo àwọn aláṣẹ yóo máa sìn ín, wọn yóo sì máa gbọ́ tirẹ̀.’


Ọlà ati ọgbọ́n ati ìmọ̀ Ọlọrun mà kúkú jinlẹ̀ pupọ o! Àwámárìídìí ni ìdájọ́ rẹ̀. Iṣẹ́ rẹ̀ tayọ ohun tí ẹ̀dá lè tú wò.


Tabi pé, oriṣa kan ti dìde rí, tí ó gbìdánwò àtifi ipá gba orílẹ̀-èdè kan fún ara rẹ̀ lọ́wọ́ orílẹ̀-èdè mìíràn, pẹlu àmì rẹ̀, ati iṣẹ́ ìyanu, ati ogun, ati agbára ati àwọn nǹkan tí ó bani lẹ́rù, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fi ojú yín rí i tí OLUWA Ọlọrun yín ṣe fun yín ní Ijipti?


Kí ọlá ati ògo jẹ́ ti Ọba ayérayé, Ọba àìkú, Ọba àìrí, Ọlọrun kan ṣoṣo, lae ati laelae. Amin.


Ṣugbọn ohun tí ó sọ fún Ọmọ náà ni pé, “Ìfẹ́ rẹ wà títí laelae, Ọlọrun, ọ̀pá òtítọ́ ni ọ̀pá ìjọba rẹ.


Ọlọrun pàápàá tún jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà nípa àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó ju agbára ẹ̀dá lọ, tí ó ṣe nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.


Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Ọlọrun ni òun ń sọ. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, kí ó ṣe é pẹlu gbogbo agbára tí Ọlọrun fún un. Ninu ohun gbogbo ẹ máa hùwà kí ògo lè jẹ́ ti Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi: òun ni ògo ati agbára jẹ́ tirẹ̀ lae ati laelae. Amin.


Angẹli keje fun kàkàkí rẹ̀, àwọn ohùn líle kan ní ọ̀run bá sọ pé, “Ìjọba ayé di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀. Yóo jọba lae ati laelae.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan