Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:22 - Yoruba Bible

22 “Ìwọ ọba ni igi yìí, ìwọ ni o dàgbà, tí o di igi ńlá, tí o sì lágbára. Òkìkí rẹ kàn dé ọ̀run, ìjọba rẹ sì kárí gbogbo ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Ọba, iwọ ni ẹniti o dagba, ti o si di alagbara: nitori titobi rẹ ga o si kan ọrun, agbara ijọba rẹ si de opin aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:22
18 Iomraidhean Croise  

Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á kọ́ ìlú ńlá kan, kí á sì kọ́ ilé ìṣọ́ gíga kan tí orí rẹ̀ yóo kan ojú ọ̀run gbọ̀ngbọ̀n, kí á baà lè di olókìkí, kí á má baà fọ́n káàkiri orí ilẹ̀ ayé.”


Nígbà tí ó sùn, ó lá àlá kan, ó rí àkàsọ̀ kan lójú àlá, wọ́n gbé e kalẹ̀, orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run. Ó wá rí i tí àwọn angẹli Ọlọrun ń gùn ún lọ sókè sódò.


Natani bá dá Dafidi lóhùn pé, “Ìwọ gan-an ni ẹni náà. Ohun tí OLUWA Ọlọrun Israẹli sì ní kí n wí fún ọ nìyí; ó ní, ‘Mo fi ọ́ jọba lórí Israẹli, mo sì gbà ọ́ kúrò lọ́wọ́ Saulu.


Wolii OLUWA kan tí ń jẹ́ Odedi wà ní ìlú Samaria; ó lọ pàdé àwọn ọmọ ogun Israẹli nígbà tí wọ́n ń pada bọ̀. Ó wí fún wọn pé, “Nítorí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín bínú sí àwọn ará Juda ni ó fi jẹ́ kí ẹ ṣẹgun wọn, ṣugbọn ẹ pa wọ́n ní ìpakúpa tóbẹ́ẹ̀ tí Ọlọrun pàápàá ṣàkíyèsí rẹ̀.


Nítorí pé ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ tóbi, ó ga ju ọ̀run lọ, òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.


OLUWA, ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ ga kan ọ̀run; òtítọ́ rẹ sì kan ojú ọ̀run.


òun ni òun fi agbára ńlá òun dá ayé: ati eniyan ati ẹranko tí wọ́n wà lórí ilẹ̀; ẹni tí ó bá tọ́ lójú òun ni òun óo sì fi wọ́n fún.


Wí fún wọn pé, OLUWA Ọlọrun ní idì ńlá kan wá sí Lẹbanoni, apá rẹ̀ tóbi, ìrù rẹ̀ sì gùn, ó sì ní ìyẹ́ aláràbarà. Ó bá bà lé ṣóńṣó orí igi kedari kan,


Òun ní ń yí ìgbà ati àkókò pada; òun níí mú ọba kan kúrò lórí ìtẹ́, tíí sì í fi òmíràn jẹ. Òun níí fi ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n tíí sì í fi ìmọ̀ fún àwọn ọ̀mọ̀ràn.


Igi náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi, ó sì lágbára; orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run, kò sí ibi tí wọn kò ti lè rí i ní gbogbo ayé.


tí ewé rẹ̀ lẹ́wà, tí ó so jìnwìnnì, tí èso rẹ̀ jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹ̀dá, tí gbogbo àwọn ẹranko ń gbé abẹ́ rẹ̀, tí àwọn ẹyẹ sì ń sùn lórí àwọn ẹ̀ka rẹ̀.


Ní ìparí oṣù kejila, bí ó ti ń rìn lórí òrùlé ààfin Babiloni,


“Ní àkókò gan-an tí iyè mi pada bọ̀ sípò, ògo, ọlá, ati iyì ìjọba mi náà sì tún pada sọ́dọ̀ mi. Àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ìjòyè mi wá mi kàn, wọ́n gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀, ìjọba mi tún fi ìdí múlẹ̀, mo sì níyì ju ti àtẹ̀yìnwá lọ ní gbogbo ọ̀nà.


Nítorí Johanu sọ fún Hẹrọdu pé kò tọ́ fún un láti fi Hẹrọdiasi ṣaya.


Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga dé ọ̀run, Ọlọrun kò gbàgbé àìṣedéédé rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan