Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:19 - Yoruba Bible

19 Ọkàn Daniẹli, tí wọn ń pè ní Beteṣasari, pòrúúruù fún ìgbà díẹ̀, ẹ̀rù sì bà á. Ọba bá sọ fún un pé: “Má jẹ́ kí àlá yìí ati ìtumọ̀ rẹ̀ bà ọ́ lẹ́rù.” Beteṣasari dáhùn pé, “olúwa mi, kí àlá yìí ṣẹ mọ́ àwọn tí wọ́n kórìíra rẹ lára, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì dà lé àwọn ọ̀tá rẹ lórí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

19 Nigbana ni Danieli, ẹniti a npè ni Belteṣassari wà ni ìwariri niwọn wakati kan, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀. Ọba si dahùn wipe, Belteṣassari, máṣe jẹ ki alá na, tabi itumọ rẹ̀ ki o dãmu rẹ̀. Belteṣassari si dahùn wipe, oluwa mi! ti awọn ẹniti o korira rẹ li alá yi, ki itumọ rẹ̀ ki o si jẹ ti awọn ọta rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Nígbà náà ni Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Belṣassari, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rùbà ọ́.” Belṣassari sì dáhùn wí pé, “olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:19
27 Iomraidhean Croise  

Rakẹli wí fún baba rẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, má bínú pé n kò dìde lójú kan tí mo jókòó sí, mò ń ṣe nǹkan oṣù mi lọ́wọ́ ni.” Bẹ́ẹ̀ ni Labani ṣe wá àwọn ère oriṣa rẹ̀ títí, ṣugbọn kò rí wọn.


Kí o wí pé, ‘Ti Jakọbu iranṣẹ rẹ ni, wọ́n sì jẹ́ ẹ̀bùn tí ó fi ranṣẹ sí Esau oluwa rẹ̀, òun alára ń bọ̀ lẹ́yìn.’ ”


Josẹfu bá sọ fún un pé, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn ẹ̀ka mẹta tí o rí dúró fún ọjọ́ mẹta.


Bí Ọbadaya ti ń lọ, lójijì ni ó pàdé Elija. Ó ranti rẹ̀, ó dojúbolẹ̀, ó kí i tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó sì bi í léèrè pé, “Àbí ìwọ kọ́ ni, Elija, oluwa mi?”


ṣugbọn OLUWA, jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pa orúkọ mi rẹ́ patapata kúrò ninu ìwé tí o kọ orúkọ àwọn eniyan rẹ sí.”


Ẹ máa wá alaafia ìlú tí mo ko yín lọ, ẹ máa gbadura sí OLUWA fún un, nítorí pé ninu alaafia rẹ̀ ni ẹ̀yin náà yóo ti ní alaafia.


Oró ò! Oró ò! Mò ń jẹ̀rora! Àyà mi ò! Àyà mi ń lù kìkìkì, n kò sì lè dákẹ́; nítorí mo gbọ́ ìró fèrè ogun, ati ariwo ogun.


Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego.


Ọba bi Daniẹli, tí wọ́n sọ ní Beteṣasari ní èdè Babiloni pé, “Ǹjẹ́ o lè rọ́ àlá mi fún mi, kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀?”


Kabiyesi, ìwọ ọba àwọn ọba ni Ọlọrun ọ̀run fún ní ìjọba, agbára, ipá ati ògo.


“Kabiyesi, ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: Àṣẹ tí Ẹni Gíga Jùlọ pa nípa oluwa mi, ọba ni.


nítorí pé Daniẹli, tí ọba sọ ní Beteṣasari, ní ìmọ̀ ati òye láti túmọ̀ àlá, ati láti ṣe àlàyé ohun ìjìnlẹ̀, ati láti yanjú ọ̀rọ̀ tí ó bá díjú. Ranṣẹ pe Daniẹli yìí, yóo sì sọ ìtumọ̀ fún ọ.”


“Kabiyesi, Ọlọrun tí ó ga jùlọ fún Nebukadinesari, baba rẹ ní ìjọba, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó fún un ní ògo ati ọlá.


Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀.


“Ìran tí mo rí yìí bà mí lẹ́rù pupọ, ọkàn mi sì dààmú.


“Òpin ọ̀rọ̀ nípa ìran náà nìyí. Ẹ̀rù èrò ọkàn mi bà mí gidigidi, tóbẹ́ẹ̀ tí ojú mi yipada, ṣugbọn inú ara mi ni mo mọ ọ̀rọ̀ náà sí.”


Àárẹ̀ mú èmi Daniẹli, mo sì ṣàìsàn fún ọpọlọpọ ọjọ́. Nígbà tó yá, mo bá tún dìde, mò ń bá iṣẹ́ tí ọba yàn mí sí lọ, ṣugbọn ìran náà dẹ́rù bà mí, kò sì yé mi.


Nígbà tí àwọn òkè ńlá rí ọ, wọ́n wárìrì; àgbàrá omi wọ́ kọjá; ibú òkun pariwo, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.


Hana dá a lóhùn, pé, “Rárá o, oluwa mi, n kò fẹnu kan ọtí waini tabi ọtí líle. Ìbànújẹ́ ló bá mi, tóbẹ́ẹ̀ tí mo fi ń gbadura, tí mo sì ń tú ọkàn mi jáde fún OLUWA.


Dafidi jáde, ó pè é, ó ní, “Olúwa mi ọba,” bí Saulu ti wo ẹ̀yìn ni Dafidi dojúbolẹ̀ láti bọ̀wọ̀ fún un.


Dafidi dáhùn pé, “Ǹjẹ́ ìwọ kọ́ ni alágbára jùlọ ní Israẹli? Kí ló dé tí o kò dáàbò bo ọba, oluwa rẹ? Láìpẹ́ yìí ni ẹnìkan wọ inú àgọ́ yín láti pa oluwa rẹ.


Eli bi í pé, “Kí ni OLUWA wí fún ọ, má fi nǹkankan pamọ́ fún mi. OLUWA yóo ṣe sí ọ jù bí ó ti sọ fún ọ lọ, bí o bá fi nǹkankan pamọ́ fún mi ninu ohun tí ó sọ fún ọ.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan