Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:18 - Yoruba Bible

18 “Ìran tí èmi Nebukadinesari rí nìyí. Ìwọ Beteṣasari, sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ìjọba mi kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣugbọn o lè ṣe é, nítorí pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Alá yi li emi Nebukadnessari lá, njẹ nisisiyi, iwọ Belteṣassari, sọ itumọ rẹ̀ fun mi, bi gbogbo awọn ọlọgbọ́n ijọba mi kò ti le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn iwọ le ṣe e; nitori ẹmi Ọlọrun mimọ́ mbẹ lara rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 “Èyí ni àlá tí èmi Nebukadnessari ọba lá. Ní ìsinsin yìí ìwọ Belṣassari, sọ ohun tí ó túmọ̀ sí fún mi, nítorí kò sí amòye kan ní ìjọba mi, tí ó lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ìwọ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí tí ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà ní inú rẹ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:18
14 Iomraidhean Croise  

Josẹfu bá sọ fún un pé, “Ìtumọ̀ rẹ̀ nìyí: àwọn ẹ̀ka mẹta tí o rí dúró fún ọjọ́ mẹta.


Farao sọ fún un pé, “Mo lá àlá kan, kò sì tíì sí ẹni tí ó lè túmọ̀ rẹ̀. Wọ́n bá sọ fún mi pé, bí o bá gbọ́ àlá, o óo lè túmọ̀ rẹ̀.”


Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, ìdààmú bá Farao, ó bá ranṣẹ lọ pe gbogbo àwọn adáhunṣe ati àwọn amòye ilẹ̀ Ijipti, ó rọ́ àlá náà fún wọn, kò sì sí ẹnìkan ninu wọn tí ó lè túmọ̀ rẹ̀ fún un.


Ìrẹ̀wẹ̀sì yóo dé bá àwọn ará Ijipti, n óo sọ ète wọn di òfo. Wọn yóo lọ máa wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ àwọn oriṣa ati àwọn aláfọ̀ṣẹ ati lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, ati àwọn oṣó.


Ninu gbogbo ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí ọba bi wọ́n, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn pidánpidán ati àwọn aláfọ̀ṣẹ tí ó wà ní ìjọba rẹ̀ lọ.


Ọlọrun fi gbogbo eniyan jìn ọ́, níbi yòówù tí wọn ń gbé, ati gbogbo ẹranko, ati gbogbo ẹyẹ, pé kí o máa jọba lórí wọn, ìwọ ni orí wúrà náà.


Wọ́n dá ọba lóhùn lẹẹkeji pé, “Kí kabiyesi rọ́ àlá rẹ̀ fún wa, a óo sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”


Gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ati aláfọ̀ṣẹ wá siwaju mi, wọ́n gbìyànjú láti ka àkọsílẹ̀ yìí, kí wọ́n sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi, ṣugbọn kò sí ẹni tí ó lè ṣe é.


Gbogbo àwọn amòye ọba wá, wọn kò lè ka àwọn àkọsílẹ̀ náà, wọn kò sì lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba.


“Dájúdájú OLUWA Ọlọrun kì í ṣe ohunkohun láì kọ́kọ́ fi han àwọn wolii, iranṣẹ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan