Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 4:17 - Yoruba Bible

17 Láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ ni ìdájọ́ yìí ti wá, ìpinnu náà jẹ́ ti àwọn Ẹni Mímọ́; kí gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù ú níí máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́, pàápàá láàrin àwọn ẹni tí ó rẹlẹ̀ jùlọ.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

17 Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

17 “ ‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 4:17
30 Iomraidhean Croise  

A óo lé ọ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan, o óo sì máa bá àwọn ẹranko inú igbó gbé; o óo máa jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì yóo sì sẹ̀ sí ọ lára fún ọdún meje, títí tí o óo fi mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹni tí ó bá wù ú níí sì í gbé e lé lọ́wọ́.


Òun ní ń yí ìgbà ati àkókò pada; òun níí mú ọba kan kúrò lórí ìtẹ́, tíí sì í fi òmíràn jẹ. Òun níí fi ọgbọ́n fún ọlọ́gbọ́n tíí sì í fi ìmọ̀ fún àwọn ọ̀mọ̀ràn.


OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀; ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀, láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba, kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá. Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé, òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn.


bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun yan àwọn ẹni tí kò níláárí ati àwọn ẹni tí kò já mọ́ nǹkankan rárá, àwọn tí ẹnikẹ́ni kò kà sí, láti rẹ àwọn tí ayé ń gbé gẹ̀gẹ̀ sílẹ̀.


Angẹli náà tún ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ báyìí pé, “Ọba tí yóo tún jẹ ní Siria yóo jẹ́ ọba burúkú. Kì í ṣe òun ni oyè yóo tọ́ sí, ṣugbọn yóo dé lójijì, yóo sì fi àrékérekè gba ìjọba.


ṣugbọn ìdí pataki tí òun fi jẹ́ kí wọ́n wà láàyè ni láti fi agbára òun hàn Farao, kí wọ́n lè máa ròyìn orúkọ òun OLUWA káàkiri gbogbo ayé.


N óo gbẹ̀san lára wọn lọpọlọpọ; n óo fi ìrúnú fi ìyà ńlá jẹ wọ́n. Wọn óo wá mọ̀ nígbà tí mo bá gbẹ̀san lára wọn pé èmi ni OLUWA.”


N óo kó àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n burú jùlọ wá, wọn óo wá gba ilé wọn. N óo fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára wọn, wọn yóo sì sọ àwọn ibi mímọ́ wọn di eléèérí.


Ekinni ń ké sí ekeji pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni OLUWA àwọn ọmọ ogun; gbogbo ayé kún fún ògo rẹ̀.”


OLUWA ti fi ara rẹ̀ hàn, ó ti ṣe ìdájọ́, àwọn eniyan burúkú sì ti kó sinu tàkúté ara wọn.


(Kò sí ẹni tí ó fi ara rẹ̀ fún iṣẹ́ burúkú lójú OLUWA gẹ́gẹ́ bíi Ahabu, tí Jesebẹli aya rẹ̀, ń tì gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láti ṣe iṣẹ́ burúkú.


Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin náà ní apá mẹfa. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní ọpọlọpọ ojú. Wọn kì í sinmi tọ̀sán-tòru, wọ́n ń wí pé, “Mímọ́! Mímọ́! Mímọ́! Oluwa Ọlọrun Olodumare. Ẹni tí ó ti wà, tí ó wà nisinsinyii, tí ó sì ń bọ̀ wá.”


Mo sọ fún ọ, níwájú Ọlọrun ati Kristi Jesu, ati àwọn angẹli tí Kristi ti yàn, pé kí o pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́; má ṣe ojuṣaaju.


Mo wá gbọ́ ohùn OLUWA ó ní, “Ta ni kí n rán? Ta ni yóo lọ fún wa?” Mo bá dáhùn, mo ní: “Èmi nìyí, rán mi.”


Àwọn eniyan burúkú ń yan kiri, níwọ̀n ìgbà tí àwọn eniyan ń ṣe àpọ́nlé iṣẹ́ ibi.


Ní àkókò ìyọnu Ahasi ọba, ó túbọ̀ ṣe alaiṣootọ sí OLUWA ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.


Gbogbo eniyan níláti fi ara wọn sí abẹ́ àwọn aláṣẹ ìlú, nítorí kò sí àṣẹ kan àfi èyí tí Ọlọrun bá lọ́wọ́ sí. Àwọn aláṣẹ tí ó sì wà, Ọlọrun ni ó yàn wọ́n.


OLUWA ti gbé ìtẹ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́run, ó sì jọba lórí ohun gbogbo.


Ó tọ́ lójú mi láti fi àmì ati iṣẹ́ ìyanu, tí Ọlọrun tí ó ga jùlọ ṣe fún mi, hàn.


Yóo sọ̀rọ̀ òdì sí Ẹni Gíga Jùlọ, yóo sì dá àwọn eniyan mímọ́, ti Ẹni Gíga Jùlọ lágara. Yóo gbìyànjú láti yí àkókò ati òfin pada. A óo sì fi wọ́n lé e lọ́wọ́ fún ọdún mẹta ati ààbọ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan