Daniẹli 4:1 - Yoruba Bible1 Ọba Babiloni ranṣẹ sí gbogbo àwọn eniyan, ati gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ní gbogbo ayé, pé: “Kí alaafia wà pẹlu yín! Faic an caibideilBibeli Mimọ1 NEBUKADNESSARI ọba, si gbogbo enia, orilẹ, ati ède, ti o ngbe gbogbo agbaiye; ki alafia ki o ma pọ̀ si i fun nyin. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Nebukadnessari ọba, Sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé: Kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i fún un yín. Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀! Faic an caibideil |
Ọjọ́ kẹtalelogun oṣù kẹta, tíí ṣe oṣù Sifani ni Modekai pe àwọn akọ̀wé ọba, wọ́n sì kọ òfin sílẹ̀ nípa àwọn Juu gẹ́gẹ́ bí Modekai ti sọ fún wọn. Wọ́n fi ranṣẹ sí àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn gomina, ati àwọn olórí àwọn agbègbè, láti India títí dé Etiopia, gbogbo wọn jẹ́ agbègbè mẹtadinlaadoje (127). Wọ́n kọ ọ́ sí agbègbè kọ̀ọ̀kan ati ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní èdè wọn, wọ́n sì kọ sí àwọn Juu náà ní èdè wọn.