Daniẹli 3:7 - Yoruba Bible7 Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró àwọn ohun èlò orin náà, gbogbo wọn wólẹ̀, wọ́n sì sin ère wúrà tí Nebukadinesari, ọba gbé kalẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ7 Nitorina, lakokò na nigbati gbogbo enia gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, ati oniruru orin gbogbo, gbogbo enia, orilẹ, ati ède wolẹ, nwọn si tẹriba fun ere wura na ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀. Faic an caibideil |
Ẹranko tí o rí yìí ti wà láàyè nígbà kan rí, ṣugbọn kò sí láàyè mọ́ nisinsinyii. Ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò, tí yóo gòkè wá láti inú ọ̀gbun jíjìn, tí yóo wá lọ sí ibi ègbé. Nígbà tí wọ́n bá rí ẹranko náà ẹnu yóo ya àwọn tí ó ń gbé orí ilẹ̀ ayé, tí a kò kọ orúkọ wọn sinu ìwé ìyè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé wá, nítorí ó ti wà láàyè, ṣugbọn kò sí láàyè nisinsinyii, ṣugbọn yóo tún pada yè.