Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:6 - Yoruba Bible

6 Ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó sin ère náà, lẹsẹkẹsẹ ni a óo gbé e sọ sinu adágún iná.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Ẹniti kò ba si wolẹ̀, ki o si tẹriba, lojukanna li a o gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:6
20 Iomraidhean Croise  

ó wo ìhà ibi tí Sodomu ati Gomora wà, ati gbogbo àfonífojì náà, ó rí i pé gbogbo rẹ̀ ń yọ èéfín bí iná ìléru ńlá.


O kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bọ wọ́n; nítorí Ọlọrun tí í máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ẹ̀ṣẹ̀ baba bi ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ẹkẹrin lára àwọn tí wọ́n kórìíra mi.


Yóo fi èyí tí ó kù gbẹ́ ère oriṣa rẹ̀, yóo máa foríbalẹ̀ fún un, yóo máa bọ ọ́, yóo máa gbadura sí i pé, “Gbà mí, nítorí ìwọ ni Ọlọrun mi.”


Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni yóo máa fi ọ̀rọ̀ wọn ṣépè fún eniyan pé: ‘OLUWA yóo ṣe ọ́ bíi Sedekaya ati Ahabu tí ọba Babiloni sun níná,’


Ṣugbọn ọba dá wọn lóhùn, pé, “Ohun tí mo bá sọ abẹ ni ó gé e; bí ẹ kò bá lè rọ́ àlá náà fún mi, kí ẹ sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fà yín ya ní tapá-titan, ilé yín yóo sì di àlàpà.


ati pé ẹnikẹ́ni tí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná tí ń jó.


Nisinsinyii, bí ẹ bá ti gbọ́ ìró ipè, fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, tí ẹ bá wólẹ̀, tí ẹ sì sin ère tí mo ti yá, ó dára, ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò wólẹ̀, wọn óo gbe yín sọ sinu adágún iná ìléru. Kò sì sí ọlọrun náà tí ó lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”


Wọ́n di àwọn mẹtẹẹta pẹlu agbádá, ati aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati fìlà wọn, ati àwọn aṣọ wọn mìíràn, wọ́n sì sọ wọ́n sí ààrin adágún iná tí ń jó.


Nítorí náà, nígbà tí wọ́n gbọ́ ìró àwọn ohun èlò orin náà, gbogbo wọn wólẹ̀, wọ́n sì sin ère wúrà tí Nebukadinesari, ọba gbé kalẹ̀.


Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀.


gbogbo àwọn alabojuto, àwọn olórí, àwọn ìgbìmọ̀, ati àwọn gomina kó ara wọn jọ, wọ́n sì fi ohùn ṣọ̀kan pé kí ọba ṣe òfin kan pé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ òun ọba. Ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kabiyesi, kí wọ́n jù ú sinu ihò kinniun.


Wọn yóo sọ wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.


wọn yóo jù wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.”


Ó bá sọ fún un pé, “Gbogbo nǹkan wọnyi ni n óo fún ọ bí o bá wolẹ̀ tí o júbà mi.”


Lẹsẹkẹsẹ ọba rán ọmọ-ogun kan, ó pàṣẹ fún un kí ó gbé orí Johanu wá. Ó bá lọ, ó bẹ́ ẹ lórí ninu ilé ẹ̀wọ̀n.


Èéfín iná oró àwọn tí wọ́n bá júbà ẹranko náà ati ère rẹ̀, tí wọ́n gba àmì orúkọ rẹ̀, yóo máa rú títí lae. Kò ní rọlẹ̀ tọ̀sán-tòru.”


Ó ṣí kànga náà, èéfín bá yọ láti inú kànga yìí, ó dàbí èéfín iná ìléru ńlá. Oòrùn ati ojú ọ̀run bá ṣókùnkùn nítorí èéfín tí ó jáde láti inú kànga náà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan