Daniẹli 3:30 - Yoruba Bible30 Ọba bá gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sí ipò gíga ní ìgbèríko Babiloni. Faic an caibideilBibeli Mimọ30 Nigbana ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego leke ni igberiko Babeli. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní30 Nígbà náà ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ga ní gbogbo agbègbè ìjọba Babeli. Faic an caibideil |
Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ni mo sọ pé, mo ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀ pé, ìdílé rẹ ati ìdílé baba rẹ ni yóo máa jẹ́ alufaa mi títí lae. Ṣugbọn nisinsinyii, èmi OLUWA náà ni mo sì tún ń sọ pé, kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n bá bu ọlá fún mi ni n óo máa bu ọlá fún, àwọn tí wọn kò bá kà mí sí, n kò ní ka àwọn náà sí.