Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:3 - Yoruba Bible

3 Nítorí náà, gbogbo wọn wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère náà, wọ́n sì dúró níwájú rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Nigbana li awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko pejọ si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari gbe kalẹ, nwọn si duro niwaju ere ti Nebukadnessari gbé kalẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn onímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba, wọn péjọ láti ya ère tí Nebukadnessari ọba gbé kalẹ̀ sí mímọ́, gbogbo wọn sì dúró síwájú u rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:3
11 Iomraidhean Croise  

Ó pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn olórí ati àwọn gomina, àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn akápò, àwọn onídàájọ́ ati àwọn alákòóso ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè Babiloni wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí òun gbé kalẹ̀.


Gbogbo àwọn baálẹ̀ ìgbèríko, àwọn olórí, àwọn gomina, ati àwọn ìgbìmọ̀ ọba, kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí i pé iná kò jó àwọn ọkunrin wọnyi, irun orí wọn kò rùn, ẹ̀wù wọn kò yipada, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tilẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn.


Akéde bá kígbe sókè, ó kéde pé, “Ọba ní kí á pàṣẹ fun yín, gbogbo eniyan, ẹ̀yin orílẹ̀, ati oniruuru èdè


Kò sí ẹni tí òye yé, kò sí ẹni tí ó ń wá Ọlọrun.


Ète kanṣoṣo ni wọ́n ní. Wọn yóo fi agbára wọn ati àṣẹ wọn fún ẹranko náà.


Nítorí Ọlọrun fi sí ọkàn wọn láti ní ète kan náà, pé àwọn yóo fi ìjọba àwọn fún ẹranko náà títí gbogbo ohun tí Ọlọrun ti sọ yóo fi ṣẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan