Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:25 - Yoruba Bible

25 Ó ní, “Ẹ wò ó, eniyan mẹrin ni mo rí yìí, wọ́n wà ní títú sílẹ̀, wọ́n ń rìn káàkiri láàrin iná, iná kò sì jó wọn, Ìrísí ẹni kẹrin dàbí ti ẹ̀dá ọ̀run.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

25 O si dahùn wipe, Wò o, mo ri ọkunrin mẹrin ni titu, nwọn sì nrin lãrin iná, nwọn kò si farapa, ìrisi ẹnikẹrin si dabi ti Ọmọ Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

25 Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹni kẹrin dàbí ọmọ Ọlọ́run.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:25
20 Iomraidhean Croise  

Ní ọjọ́ kan, àwọn ọmọ Ọlọrun wá láti fi ara wọn hàn níwájú OLUWA. Satani náà wà láàrin wọn.


tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ ń jùmọ̀ kọrin, tí gbogbo àwọn ọmọ Ọlọrun sì búsáyọ̀?


Yóo gbà ọ́ lọ́wọ́ ìnira lọpọlọpọ ìgbà, bí ibi ń ṣubú lu ara wọn, kò ní dé ọ̀dọ̀ rẹ.


Angẹli OLUWA yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, a sì máa gbà wọ́n.


Ta ló ti lọ sí ọ̀run rí, tí ó sì tún pada wá? Ta ló ti kó afẹ́fẹ́ jọ sí ọwọ́ rẹ̀? Ta ló ti fi aṣọ rẹ̀ di omi? Ta ló fi ìdí gbogbo òpin ayé múlẹ̀? Kí ni orúkọ olúwarẹ̀? Kí sì ni orúkọ ọmọ rẹ̀? Ṣé o mọ̀ ọ́n!


Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá, n óo wà pẹlu rẹ; nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá, kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀, nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ. Ahọ́n iná kò ní jó ọ run.


Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ. Nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́ kalẹ̀. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Má bẹ̀rù wọn, nítorí mo wà pẹlu rẹ, n óo sì gbà ọ́.”


N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú, n óo sì rà ọ́ pada lọ́wọ́ àwọn ìkà, aláìláàánú eniyan.”


Ṣugbọn bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a kò ní fi orí balẹ̀, kí á sin ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀.”


Lójijì Nebukadinesari ta gìrì, ó sáré dìde, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Ṣebí eniyan mẹta ni a dì, tí a gbé sọ sinu iná?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kabiyesi.”


Nebukadinesari bá dáhùn pé “Ògo ni fún Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e, tí wọn kò ka àṣẹ ọba sí, tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu, dípò kí wọ́n sin ọlọrun mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọrun wọn.


Inú ọba dùn pupọ, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n yọ Daniẹli jáde. Wọ́n bá yọ Daniẹli jáde kúrò ninu ihò kinniun, àwọn kinniun kò sì pa á lára rárá, nítorí pé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun rẹ̀.


wọn yóo gbé ejò lọ́wọ́, wọn yóo mu òògùn olóró, ṣugbọn kò ní ṣe wọ́n léṣe; wọn yóo gbé ọwọ́ lé àwọn aláìsàn, ara wọn yóo sì dá.”


Angẹli náà dá a lóhùn pé, “Ẹ̀mí Mímọ́ yóo tọ̀ ọ́ wá, agbára Ọ̀gá Ògo yóo ṣíji bò ọ́. Nítorí náà Ọmọ Mímọ́ Ọlọrun ni a óo máa pe ọmọ tí ìwọ óo bí.


Paulu kàn gbọn ejò náà sinu iná ni, ohun burúkú kan kò sì ṣẹlẹ̀ sí i.


Ọmọ rẹ̀ yìí ni Ọlọrun fi agbára Ẹ̀mí Mímọ́ yàn nígbà tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú. Òun náà ni Jesu Kristi Oluwa wa,


Ta ni lè ṣe yín ní ibi tí ẹ bá ní ìtara fún ohun tíí ṣe rere?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan