Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:23 - Yoruba Bible

23 Nítorí dídì tí wọ́n di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, wọ́n ṣubú lulẹ̀ sí ààrin iná náà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

23 Ṣugbọn awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, ṣubu lulẹ ni didè si ãrin iná ileru ti njo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ṣubú lulẹ̀ sínú iná ìléru náà pẹ̀lú bí a ṣe dè wọ́n.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:23
13 Iomraidhean Croise  

Ìpọ́njú olódodo a máa pọ̀; ṣugbọn OLUWA a máa kó o yọ ninu gbogbo wọn.


Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá, n óo wà pẹlu rẹ; nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá, kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀, nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ. Ahọ́n iná kò ní jó ọ run.


Wọ́n bá mú Jeremaya, wọ́n jù ú sinu kànga Malikaya, ọmọ ọba, tí ó wà ní gbọ̀ngàn àwọn tí wọn ń ṣọ́ ààfin. Wọ́n fi okùn sọ Jeremaya kalẹ̀ sinu kànga náà, kò sí omi ninu rẹ̀, àfi ẹrẹ̀ nìkan, Jeremaya sì rì sinu ẹrẹ̀ náà.


Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego.


Lójijì Nebukadinesari ta gìrì, ó sáré dìde, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Ṣebí eniyan mẹta ni a dì, tí a gbé sọ sinu iná?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kabiyesi.”


Ìjìyà wa mọ níwọ̀n, ati pé fún àkókò díẹ̀ ni. Àyọrísí rẹ̀ ni ògo tí ó pọ̀ pupọ, tí yóo wà títí, tí ó sì pọ̀ ju ìyà tí à ń jẹ lọ.


Wọ́n pa iná ńlá. Wọ́n bọ́ lọ́wọ́ idà. A sọ wọ́n di alágbára nígbà tí wọn kò ní ìlera. Wọ́n di akọni lójú ogun. Wọ́n tú àwọn ọmọ-ogun ilẹ̀ àjèjì ká tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá pada sẹ́yìn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan