Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:22 - Yoruba Bible

22 Nítorí bí àṣẹ ọba ti le tó, ati bí adágún iná náà ti gbóná tó, ahọ́n iná tí ń jó bùlàbùlà jó àwọn tí wọ́n gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sinu rẹ̀ ní àjópa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Nitorina bi aṣẹ ọba ti le to, ati bi ileru na si ti gboná gidigidi to, ọwọ iná na si pa awọn ọkunrin ti o gbé Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Nítorí bí àṣẹ ọba ṣe le tó, tí iná ìléru náà sì gbóná, ọwọ́ iná pa àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:22
10 Iomraidhean Croise  

Ó bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ gùn, ó gbọ̀nà, ó sì rí òkú wolii náà nílẹ̀ lójú ọ̀nà, níbi tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ati kinniun náà ti dúró tì í. Kinniun yìí kò jẹ òkú rẹ̀ rárá bẹ́ẹ̀ ni kò sì ṣe kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní ohunkohun.


Àwọn ará Ijipti bá ń kán àwọn eniyan náà lójú láti tètè máa lọ. Wọ́n ní bí wọn kò bá tètè lọ, gbogbo àwọn ni àwọn yóo di òkú.


OLUWA a máa gba olódodo lọ́wọ́ ìyọnu, ṣugbọn ẹni ibi a bọ́ sinu wahala.


Eniyan burúkú ni yóo forí gba ibi tíì bá dé bá olódodo. Alaiṣootọ ni yóo fara gba ìyà tí ó tọ́ sí olóòótọ́ inú.


Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego.


ó ní, “Kí ló dé tí àṣẹ ọba fi le tó báyìí?” Arioku bá sọ bí ọ̀rọ̀ ti rí fún un.


Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú gbogbo àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kan Daniẹli, ati àwọn ọmọ wọn, ati àwọn aya wọn, wọ́n bá dà wọ́n sinu ihò kinniun. Kí wọn tó dé ìsàlẹ̀, àwọn kinniun ti bò wọ́n mọ́lẹ̀, wọ́n sì fọ́ egungun wọn túútúú.


Judasi bá da owó náà sílẹ̀ ninu Tẹmpili, ó jáde, ó bá lọ pokùnso.


Hẹrọdu wá Peteru títí, ṣugbọn kò rí i. Lẹ́yìn tí ó ti wádìí lẹ́nu àwọn ẹ̀ṣọ́ tán, ó ní kí wọ́n pa wọ́n. Ni Hẹrọdu bá kúrò ní Judia, ó lọ sí Kesaria, ó lọ gbé ibẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan