Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:21 - Yoruba Bible

21 Wọ́n di àwọn mẹtẹẹta pẹlu agbádá, ati aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati fìlà wọn, ati àwọn aṣọ wọn mìíràn, wọ́n sì sọ wọ́n sí ààrin adágún iná tí ń jó.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Nigbana ni a dè awọn ọkunrin wọnyi ti awọn ti agbáda, ṣokoto, ati ibori wọn, ati ẹwu wọn miran, a si gbé wọn sọ si ãrin iná ileru ti njo.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Nígbà náà ni a dè wọ́n pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn, ṣòkòtò, ìbòrí àti àwọn aṣọ mìíràn, a sì jù wọ́n sínú iná ìléru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:21
6 Iomraidhean Croise  

ó sì sọ Josẹfu sinu ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ibi tí wọn ń ti àwọn tí ọba bá sọ sí ẹ̀wọ̀n mọ́ ni wọ́n tì í mọ́.


Gbogbo àwọn ará Juda tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ní Babiloni yóo máa fi ọ̀rọ̀ wọn ṣépè fún eniyan pé: ‘OLUWA yóo ṣe ọ́ bíi Sedekaya ati Ahabu tí ọba Babiloni sun níná,’


Ó tún pàṣẹ pé kí àwọn akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu adágún iná.


Gbogbo àwọn baálẹ̀ ìgbèríko, àwọn olórí, àwọn gomina, ati àwọn ìgbìmọ̀ ọba, kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí i pé iná kò jó àwọn ọkunrin wọnyi, irun orí wọn kò rùn, ẹ̀wù wọn kò yipada, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tilẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn.


Ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó sin ère náà, lẹsẹkẹsẹ ni a óo gbé e sọ sinu adágún iná.”


Wọn yóo sọ wọ́n sinu iná ìléru. Níbẹ̀ ni ẹkún ati ìpayínkeke yóo wà.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan