Daniẹli 3:2 - Yoruba Bible2 Ó pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn baálẹ̀ agbègbè, àwọn olórí ati àwọn gomina, àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn akápò, àwọn onídàájọ́ ati àwọn alákòóso ati gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ọba tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè Babiloni wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí òun gbé kalẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ2 Nigbana ni Nebukadnessari ọba, ranṣẹ lọ ipè awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, ati awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko, lati wá si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari ọba, gbé kalẹ. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní2 Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn ìgbìmọ̀, àwọn baálẹ̀, àwọn balógun, àwọn onídàájọ́, àwọn olùtọ́jú ìṣúra àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba láti wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀. Faic an caibideil |