Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:18 - Yoruba Bible

18 Ṣugbọn bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a kò ní fi orí balẹ̀, kí á sin ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Ṣugbọn bi bẹ̃kọ, ki o ye ọ, ọba pe, awa kì yio sìn oriṣa rẹ, bẹ̃li awa kì yio si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:18
20 Iomraidhean Croise  

Ó bá dáhùn pé, “Mò ń jowú nítorí OLUWA, Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, nítorí pé àwọn ọmọ Israẹli ti da majẹmu rẹ̀, wọ́n ti wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀, wọ́n sì ti fi idà pa àwọn wolii rẹ̀. Èmi nìkan ṣoṣo, ni mo ṣẹ́kù, wọ́n sì fẹ́ gba ẹ̀mí èmi náà.”


Sibẹsibẹ n óo dá ẹẹdẹgbaarin (7,000) eniyan sí, ní ilẹ̀ Israẹli: àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí mi, tí wọn kò tíì kúnlẹ̀ fún oriṣa Baali, tabi kí wọ́n fi ẹnu wọn kò ó lẹ́nu.”


Wò ó, yóo pa mí; n kò ní ìrètí; sibẹ n óo wí àwíjàre tèmi níwájú rẹ̀.


Àwọn eniyan burúkú a máa sá, nígbà tí ẹnikẹ́ni kò lé wọn, ṣugbọn olódodo a máa láyà bíi kinniun.


Nebukadinesari bá dáhùn pé “Ògo ni fún Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e, tí wọn kò ka àṣẹ ọba sí, tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu, dípò kí wọ́n sin ọlọrun mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọrun wọn.


“Ẹ kò gbọdọ̀ yipada kí ẹ lọ bọ oriṣa tabi kí ẹ yá ère kankan fún ara yín. Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín.


Ẹ má bẹ̀rù àwọn tí wọ́n lè pa ara yín, tí wọn kò lè pa ẹ̀mí yín. Ẹni tí ó yẹ kí ẹ bẹ̀rù ni Ọlọrun tí ó lè pa ẹ̀mí ati ara run ní ọ̀run àpáàdì.


Ẹni tí ó bá sì fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là yóo pàdánù rẹ̀; ṣugbọn ẹni tí ó bá pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nítorí mi yóo jèrè rẹ̀.


Ó dá wọn lóhùn pé, “Nígbà tí ọjọ́ bá rọ̀, ẹ máa ń sọ pé, ‘Ojú ọjọ́ dára, nítorí ojú ọ̀run pupa.’


Ṣugbọn Peteru ati Johanu dá wọn lóhùn pé, “Èwo ni ó tọ́ níwájú Ọlọrun: kí á gbọ́ràn si yín lẹ́nu ni, tabi kí á gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu? Ẹ̀yin náà ẹ dà á rò.


Ó kúkú yàn láti jìyà pẹlu àwọn eniyan Ọlọrun jù pé kí ó jẹ ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ lọ.


Bí kò bá wá wù yín láti máa sin OLUWA, ẹ yan ẹni tí ó bá wù yín láti máa sìn lónìí. Kì báà ṣe àwọn oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò, tabi oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn ní tèmi ati ilé mi, OLUWA ni àwa óo máa sìn.”


Wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan ati ẹ̀rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n jẹ́ ṣẹgun rẹ̀. Nítorí wọn kò ka ẹ̀mí wọn sí pé ó ṣe iyebíye jù kí wọ́n kú lọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan