Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:15 - Yoruba Bible

15 Nisinsinyii, bí ẹ bá ti gbọ́ ìró ipè, fèrè, dùùrù, ìlù, hapu, ati oniruuru orin, tí ẹ bá wólẹ̀, tí ẹ sì sin ère tí mo ti yá, ó dára, ṣugbọn bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ kò wólẹ̀, wọn óo gbe yín sọ sinu adágún iná ìléru. Kò sì sí ọlọrun náà tí ó lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Njẹ bi ẹnyin ba mura pe, li akokò ti o wù ki o ṣe ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ti ẹ ba wolẹ ti ẹ ba si tẹriba fun ere wura ti mo yá, yio ṣe gẹgẹ; ṣugbọn bi ẹnyin kò ba tẹriba, a o gbé nyin ni wakati kanna sọ si ãrin iná ileru ti njo; ta li Ọlọrun na ti yio si gbà nyin kuro li ọwọ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 Ní ìsinsin yìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetán láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:15
25 Iomraidhean Croise  

Nígbà wo ni ọ̀kan ninu àwọn ọlọrun orílẹ̀-èdè wọnyi gba orílẹ̀-èdè wọn lọ́wọ́ ọba Asiria rí, tí OLUWA yóo fi gba Jerusalẹmu lọ́wọ́ mi?”


ṣugbọn OLUWA, jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, pa orúkọ mi rẹ́ patapata kúrò ninu ìwé tí o kọ orúkọ àwọn eniyan rẹ sí.”


Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ta ni OLUWA yìí tí n óo fi fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí n sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ? N kò mọ OLUWA ọ̀hún, ati pé n kò tilẹ̀ lè gbà rárá pé kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.”


Ta ni ò ń sọ̀rọ̀ aṣa sí, tí ò ń fí ń ṣe ẹlẹ́yà? Ta ni ò ń ṣíjú wò pẹlu ìgbéraga? Ṣé Ẹni Mímọ́ Israẹli ni o ṣe irú èyí sí?


Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.”


Bí ẹ kò bá rọ́ àlá mi fún mi, ìyà kanṣoṣo ni n óo fi jẹ yín. Gbogbo yín ti gbìmọ̀ pọ̀ láti máa parọ́, ati láti máa fi ọgbọ́n fi àkókò ṣòfò. Ẹ rọ́ àlá mi fún mi, n óo sì mọ̀ dájú pé ẹ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀.”


Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá.


Ọba bá pàṣẹ pé kí wọ́n lọ mú Daniẹli, kí wọ́n sì jù ú sinu ihò kinniun. Ṣugbọn ó sọ fún Daniẹli pé, “Ọlọrun rẹ tí ò ń sìn láìsinmi yóo gbà ọ́.”


Nígbà tí ó dé ẹ̀bá ibẹ̀, ó kígbe pẹlu ohùn arò, ó ní, “Daniẹli, iranṣẹ Ọlọrun Alààyè, ǹjẹ́ Ọlọrun tí ò ń sìn láìsinmi gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn kinniun?”


Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ fún ìdájọ́, ẹ má dààmú nípa ohun tí ẹ óo sọ tabi bí ẹ óo ti sọ ọ́; nítorí Ọlọrun yóo fi ohun tí ẹ óo sọ fun yín ní àkókò náà.


Ṣé ó gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun ni! Kí Ọlọrun gbà á sílẹ̀ nisinsinyii bí ó bá fẹ́ ẹ! Ṣebí ó sọ pé ọmọ Ọlọrun ni òun.”


Nígbà tí wọn bá mu yín lọ sí ibi ìdájọ́, ẹ má ṣe da ara yín láàmú nípa ohun tí ẹ óo sọ, ṣugbọn ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ bá fun yín ní wakati kan náà ni kí ẹ sọ, nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń sọ̀rọ̀ bíkòṣe Ẹ̀mí Mímọ́.


“Nígbà tí wọ́n bá mu yín lọ sinu ilé ìpàdé ati siwaju àwọn ìjòyè ati àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe dààmú nípa bí ẹ óo ti ṣe wí àwíjàre tabi pé kí ni ẹ óo sọ.


Bí ó bá so èso ní ọdún tí ń bọ̀, ó dára. Bí kò bá so èso, gé e.’ ”


Ṣugbọn Peteru ati Johanu dá wọn lóhùn pé, “Èwo ni ó tọ́ níwájú Ọlọrun: kí á gbọ́ràn si yín lẹ́nu ni, tabi kí á gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu? Ẹ̀yin náà ẹ dà á rò.


Peteru pẹlu àwọn aposteli dáhùn pé, “A níláti gbọ́ ti Ọlọrun ju ti eniyan lọ.


Gbogbo àwọn tí ó jókòó ní ìgbìmọ̀ tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí ojú rẹ̀ tí ó dàbí ojú angẹli.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan