Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Daniẹli 3:13 - Yoruba Bible

13 Inú bí ọba gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn mẹtẹẹta wá siwaju òun, wọ́n bá kó Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego lọ siwaju ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

13 Nigbana ni Nebukadnessari ọba paṣẹ ni ibinu ati irunu rẹ̀, pe, ki nwọn ki o mu Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego wá. Nigbana ni a si mu awọn ọkunrin wọnyi wá siwaju ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

13 Nígbà náà ni Nebukadnessari pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Daniẹli 3:13
15 Iomraidhean Croise  

ṣugbọn inú Ọlọrun kò dùn sí Kaini, kò sì gba ẹbọ rẹ̀. Inú bí Kaini, ó sì fa ojú ro.


Ó sàn kí eniyan pàdé ẹranko beari tí a kó lọ́mọ, ju kí ó pàdé òmùgọ̀ ninu agọ̀ rẹ̀ lọ.


Òkúta wúwo, yanrìn sì tẹ̀wọ̀n, ṣugbọn ìmúnibínú aṣiwèrè wúwo lọ́kàn ẹni ju mejeeji lọ.


Ẹni tí inú ń bí a máa dá rògbòdìyàn sílẹ̀, onínúfùfù a sì máa ṣe ọpọlọpọ àṣìṣe.


Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego.


Nítorí náà inú ọba ru, ó sì bínú gidigidi, ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n pa gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n Babiloni run.


Inú bá bí Nebukadinesari gidigidi, ojú rẹ̀ yipada sí Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá iná, kí ó gbóná ní ìlọ́po meje ju bíí tií máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ.


Wọn yóo mu yín lọ jẹ́jọ́ níwájú àwọn gomina ati níwájú àwọn ọba nítorí tèmi, kí ẹ lè jẹ́rìí mi níwájú wọn ati níwájú àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu.


“Ṣugbọn ẹ̀yin fúnra yín, ẹ kíyèsára. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọn yóo lù yín ninu àwọn ilé ìpàdé. Wọn yóo mu yín lọ siwaju àwọn aláṣẹ ati àwọn ọba nítorí mi kí ẹ lè jẹ́rìí ìyìn rere fún wọn.


Kí gbogbo èyí tó ṣẹlẹ̀, wọn yóo dojú kọ yín, wọn yóo ṣe inúnibíni si yín. Wọn yóo fà yín lọ sí inú ilé ìpàdé ati sinu ẹ̀wọ̀n. Wọn yóo fà yín lọ siwaju àwọn ọba ati àwọn gomina nítorí orúkọ mi.


Inú wọn ru sókè, wọ́n wá ń bá ara wọn jíròrò nípa ohun tí wọn ìbá ṣe sí Jesu.


Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí Fẹliksi ti dé pẹlu Durusila iyawo rẹ̀ tí ó jẹ́ Juu, ó ranṣẹ sí Paulu láti gbọ́ ọ̀rọ̀ nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu lẹ́nu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan